Peluu awuyewuye pe
boya ni idibo gbogbogbo egbe oselu PDP tipinle Ogun yoo waye nitori ase ile ejo
kan, se ni won se eto naa nirowo rese.
Ipade gbogbogbo
naa to waye ninu gbongan Obasanjo Library niluu Abeokuta lojo Satide
Abameta lawon asoju lawon ijoba ibile Ogun ti kopa nibe.
Awon olori egbe naa
lapapo lati Abuja peluu awon asoju ajo INEC ni won seto ibo lati yan awon oloye
egbe tuntun naa.
Ninu oro Dokita Eddy
Olafeso to je alaga igbimo to seto idibo naa lo ti so di mi mo pe kii se awon
fidihe ni won seto ibo naa ati pe ko si nnkan to je niwonba ti won ti fofin de
won.
O wa gba gbogbo omo
egbe nimoran lati gbagbe gbogbo nnkan to koja ki won si jo fi mo sokan.Awon
mokanlelogbon ni won dibo yan gege bi oloye tuntun fegbe oselu PDP nipinle
Ogun.
Sikirulae Ogundele lo
wole gege bi alaga naa tuntun,Nigba ti Wole Ojosipe je igbakeji e,Alaaji Ismail
Odejinmi, Kayode Adebayo ati Wale Adeogun je igbakeji alaga lati Ekun kookan to
wa nipinle Ogun.
Nigba to n soro leyin
ti won yan an gege bi alaga fegbe naa, Onarebu Sikirulae Ogundele so pe
gbogbo agbara loun yoo sa lati rii gbogbo aawo to wa ninu egbe naa di yiyanju.
Bee lo tun so pe ijoba
toun kii se adase ati pe gbogbo bi nnkan ba se n loo loun yoo maa je kawon omo
egbe gbo. O wa bebe fun ifowosowopo awon omo egbe ki ogo egbe naa le pada si bo
ti wa tele nipinle Ogun.
Alaga naa so pe Seneto
Buruji Kashamu naa ko ba wa sibi eto naa sugbon o rin irinajo. Ninu oro Onarebu
Ladi Adebutu to n soju ekun Remo nile igbimo asojusofin niluu Abuja,o ni inu
oun dun pe idibo naa loo nirowo rese ati pe awon ti setan lati jo sise po.
Sugbon oun ni tie so
pe Kasanu rin irinajo loo si America ni ko je ko wa. Ohun to tun jo ni loju
lojo naa ni bi alaga UPN tele. Arabinrin Irede Oginni atawon meji min ti won jo
wa ninu egbe se wa lara awon oloye tuntun fegbe PDP.
No comments:
Post a Comment