|
Egbe awon odo Yewa Awori iyen YAYPF
ti kilo fawon agbaagba won kan lati sora fawon oro ti won yoo maa so sita, ki
eleyii ma tun dena anfaani ekun naa lati di gomina ninu ibo to n bo lodun 2019.
Ninu atejade kan ti egbe naa gbeE
jade, eyi ti Onimo ero Demola Edun to je alaga egbe naa lapapo ati akowe e
Arabinrin Dupe Olabode fowo sii ni won tun ke si gbogbo omo bibi Yewa Awori
nile yii ati ni oke okun lati dide po gbogun tawon to fee fi imo tara eni nikan
ti won ba ojo iwaju .
Egbe odo naa tun lawon dara won ya
soto si oro ti Oloye Mohammed Ajibola Olagbaye ba awon oniroyin so lenu
ojo meta yii lori oro oselu ipinpo to se lose to koja.
Egbe YAYPF naa salaye pe inu awon ko
dun si oro kobakugbe ti eni to pe ara e ni alaga awon agbagba so si Aremo
Olusegun Osoba. Won ni awon ka oro naa si pe won wa sise owo ti won fee gba
lowo eni to ran won. Nitori lati fi dogbon pa enu awon ojulowo omo Yewa-
Awori lenu mo lori ibo to n bo lona naa.
Atejade naa tun so siwaju pe ko le
ya awon lenu lori iwa ti awon agbagba Yewa kan ti Olagbaye je alaga won hu,loro
oro ti won ni Oloye Osoba so nibi ojoobi Alagba Poju Adeyemi pe egbe
oselu APC ko pin ipo gomima si igun kankan lorile ede yii
Bee ni won tun gbogun ti gpmina tele
nipinle Ogun nitori won loun lo pon Senato Olamilekan Adeola tawon eeyan mo si
YAYI seyin lati di gomina. Won ni nnkan to dun awon ju ni pe Opo awon to n bu
Osoba lo je pe won ti je, ti won bi nigba ti Okunrin naa si je gomina nipinle
Ogun.
Egbe YAYPF ni bawon agbaagba naa ba
gbagbe awon yoo ran won leti pe Osoba ti won bu yii ni gomina akoko ti yoo fi
Yewa Awori sipo gidi, nigba to yan Alagba Poju Adeyemi sipo akowe Iwe ijoba,
laarin odun 1993 si 2003.Won ni gbogbo enu lawon fi le so pe ninu awon oloselu
to fee jade ko si eyi to lemi Olamilekan Adeola YAYI ninu won.
Won ni se won ko gbo oro Suraj
Adekunmbi so nigba kan pe awon ko fee maa maa gbena woju Amosun nitori erongba
e lati dije lodun 2019. Egbe naa wa pari oro won nipa ki kesi awon Yewa Awori
lapapo ki won jo fimo sokan,ki won maa se je kawon kan lo won nilokulo nitori
iwa imo tara eni nikan won. Won bigba teeyan ba je alaimoore niwa tawon
Olagbaye hu si Osoba ko si ye ko ri bee.
|
No comments:
Post a Comment