Oludije fun ipo gomina lodun 2011
ati 2015, Alaaji Gboyega Nasir Isiaka ti kede sita pe ko si nnkan to le di oun
lowo lati maa jade fun IPO gomina lodun 2019.
O soro yii nibi eto kan ti egbe to
sagbekale e iyen Believe Movement ti adape e n je Irorun se lati fi seto
iranlowo fawon eeyan, eyi to waye ni Aafin Alake niluu Abeokuta.
Bo tile je pe ko tii so pato egbe
oselu to fee ba jade sugbon o ti fi okan awon eeyan e bale pe ko si iberu ati
ifoya foun lati maa dupo lodun 2019.
Gboyega Isiaka soro yii lati fi tako
oro tawon kan n so pe awon ko ti mo boya Okunrin naa ni lokan lati dije fun ipo
gomina naa, O so pe lodun 2011 toun koko h oun se daadaa bee naa lodun
2015 naa oun tun se daadaa ju bee lo sugbon ireti wa foun pe ibo 2019 ni won
yoo fi gboun wole, nitori ko si ifoya foun.
Bakan naa lo tun so pe gege bi eni
to se kekere ni Imeko,toun si loo ileewe nibe, toun tun gbe peluu awon ara
igberiko oun mo nnkan to ye lati se ti yoo fi mu irorun ba awon araalu.
Okunrin tun je ko ye awon to wa nibi
eto naa bi oro araalu se ka lara to, o ni akoko ti to lati mu awon araalu kuro
ninu ainifokabale ati pe gbogbo ipenija tawon eeyan koju ni yoo di
afiseyin,leyin tijoba tuntun ba wole.
O ni gbogbo iriri oun loun yoo lo
gege bi eni to kawe gboye nipa isuna ati oro aje lati fi sakoso ipinle yii lona
to to ati pe opo awon ileese ni won setan lati da ileese sile,,o wa ni kawon
eeyan e gbaradi fun eto ibo to n bo lona naa.
Nibi eto naa ni Reuben Abati ti
dawon eeyan lekoo, ko to di pe won fawon eeyan ni awon ohun to iranwo lojo naa.
|
No comments:
Post a Comment