Awon agba Yewa ti kilo fun Gomina
Ibikunle Amosun pe ko ye pe awon kan ni Tekobo mo nitori oun gan ni olori awon
Tekobo to wa sakoso nipinle Ogun.
Oloye M A Ajibode to je alaga awon
agba awon Yewa Awori lo soro yii lakoko ti won se ipade po peluu awon oniroyin,
eyi to waye niluu Abeokuta.
O soro yii lati fi tako oro tawon
agba Yewa kan koko so lose to koja pe awon Tekobo lo fee se gomina lodun 2019.
Okunrin toun naa ti sise labe Gomina
Amosun so pe airi oro so ati pe katikati loro ti Alaaji Mohammed Olagbaye to
saaju awon agba Yewa ti Amosun naa so lose to koja ti ko si gba enu e.
O ni Olagbaye funra e ilu Eko lo ti
lo gbogbo aye e to si tun sise labe ijoba ipinle Eko. Bakan naa lo ni gbogbo
awon to ti je gomina tele nipinle Ogun ko seyi ti kii se Tekobo ninu won
Oloye Ajibola so pe kii se akoko yii
lo ye kawon agbaagba Yewa gba ki awon kan da aarin won ru lakoko ti won fee
fenu ko lati fa gomina kale.
Okunrin naa tun tako oro ti won so
pe Oloye Olusegun Osoba fee rere fun won ni Yewa,O ni awon agba to soro naa kan
jise owo ti won ran won ni ko seni to ran won nise.
O wa pada soro e pe gbogbo awon agba
naa ni enu won ko gba pe Tekobo lenikan nitori owo ti won gan ko me.
Ajibola tun salaye pe gbogbo awon to
n so isokuso yii, opo won lo ti ba Osoba sise lakoko to n sejoba,.O ni alaimore
eda lawon eeyan naa,bee ni won ko tun yato si odale.
O ni ipa pataki ni Oloye Olusegun
Osoba ti ko ninu ki Yewa di gomina lati bi odun mejilelogoji seyin.
Okunrin naa so pe bi won ba gbagbe
oun yoo ran won leti,Oloye Oloogbe Wale Bajomo ati Oloye Akin Odunsi wa lara
awon to satileyin fun lati di gomina.
O ni gbogbo awon Yewa lawon sise po
lati rii pe gbogbo egbe oselu fa oludije won kale lati Yewa.
Ninu oro Oloye Olu Agemo to ti figba
kan je alaga fegbe oselu SDP nibi ipade oniroyin naa lo ti so pe ko ye ki won
fawon kan laye lati da aarin won.
Nitori pe awon mo pe won tun ti da
awon eeyan sita ninu won lati da wahala sile, O so pe awon to ni Yewa lo kan
naa ni won tun fee maa da wahala sile.
O ni Osoba gbogbo ninu ijoba
tiwantiwa ati pe kii se nnkan Baba naa so lawon to n gbe kaakiri so,won kan fee
je ki won lo won nilokulo ni.
|
No comments:
Post a Comment