Awon alakoso fawon
agunbaniro iyen National Youth Service Corps (NYSC) ti gboriyin fun oludasile
ajo Paseda Legacy Foundation,Otunba Rotimi Paseda fun bo se nawo nara ati bo se toju
awon agunbaniro to wa sise peluu won lakoko ti won sinru iluu.
Ogbeni Okpo John to je
alakoso fawon agunbaniro nipinle Ogun lo gboriyin yii lakoko ti won sayeye
idagbere fawon tiko keji iyen Batch B ti won sise peluu ajo Paseda Legacy
naa,eyi to waye lojo Eti, Fraide ose to koja niluu Abeokuta.
Okunrin yii lo soju fun
Ogbeni Mayomi Sylvester to je igbakeji oga agba nibi ayeye naa, O so pe peluu
enu loun fi so pe itoju ti won fawon agunbaniro ko se e fenu so, ko si se
safiwe peluu awon yooku ti won gbe lati loo sise nibomin in.
O fikun oro e pe inu
oga awon agunbaniro naa dun pupo fun iroyin tawon gbo nipa ajo naa lori itoju
ti won fawon omo won naa nipinle Ogun.
Bee lo lo anfaani naa
lati fi ki awon agunbaniro ti won sayeye idagbere fun naa ku oriire aseyori ti
won laarin odun kan ti won fi sin ile baba won naa.
O wa gbawon nimoran
lati rii pe won lo awon iriri ti won ti ri lakoko ti won fi se agunbaniro naa
gege eyi ti won yoo maa fi se amulo nibi gbogbo ti won ba ti n sise.
O ni Otunba Paseda ti
je kawon mo pe adari rere to nifee si eto eko ni sugbon o ni yoo dun mo awon
ninu tiru nnkan bee ba tun tesiwaju peluu awon agunbaniro yooku ti won wa ni
Abeokuta.
Ninu oro tie, nibi
ayeye naa, Otunba Rotimi Paseda so pe awon agunbaniro ti kopa to joju
lorile ede yii bee lo tun je ki isokan wa laarin awon odo.
No comments:
Post a Comment