O wa lara awon osise meta to kede
lati baa sise po gege bi Aare ona kankafo. Awon meji yooku ni Oloye Femi Davies
ati Alagba Femi Adepoju.
Femi Davies lo dipo oludamoran lori
awon akanse ayeye nigba ti Femi Adepoju wa fun eto Iroyin.Ko to di pe IOmooba
Segun Akanni depo yii, oun ni amugbalegbe fun Aare ona kankafo iyen Otunba Gani
Adams.
Idile Oba ni a bi si ni Ileogbo ni
Ayedire nipinle Osun.Nibe naa lo ti loo sileewe alakobere ati ti girama. Bakan
naa lo gboye imo ijinle lori ise ajosepo ati isakoso iyen Industrial
Relations and Personnel Management (IRPM nileewe giga yunfasiti tipinle Eko,
Lagos State University, LASU to wa nu Ojo, Eko.
Segun Akanni tun loo kekoo nipa
isakoso irinajo afe lorile ede Ghana.Odun 1998 lo darapo mo egbe Oodua People's
Congress iyen OPC ni Ijesa tedo, ko pe sigba naa lo loo darapo mo tawon
eeyan Ojo nibi to ti mu ise naa lokunkundun, to si je akowe ni ekun Tedi.
Sugbon nigba ti yoo fi di odun 1999,
o ti gba igbega si akowe olupolongo nijoba ibile Ojo. .Nitori akitiyan atawon
ipa ribiribi to ti ko fun ijagbara omo Yoruba lo je ki ofiisi alakoso
fegbe OPC fi so di amugbalegbe ati oluranlowo fun eto Iroyin fun Otunba Gani
Adams lodun 2002.
Lodun 2007 ni Akanni kuku wa di
amugbalegbe patapata fun Otunba Gani Adams ipo to wa titi digba ti won fi fun
nipo gidi gege olori osise fun Aare ona kankafo tuntun.
Omooba Segun Akanni tun ti ni
anfaani lati loo sawon orile ede bii aadota fun titan ihinrere Oodua
Progressive Union (OPU) peluu Aare Onakakanfo,
Bee naa ni Okunrin yii naa ti figba
kowe lati fi saponle Oga e, Otunba Gani Adams lodun 2015, akole Iwe naa lo pe
ni The Volunteer of Savanah ni ede oyinbo.
Olori awon osise ni iyawo bee naa n
Olorun jogun omo fun in.
|
No comments:
Post a Comment