Egbe agbagba ile Yewa ti ke gbajare
faraye pe kawon eeyan gba awon lowo Oloye Olusegun Osoba to ti figba kan je
gomina nipinle Ogun tele lori bi ko se ro rere kan awon lati di gomina lodun 2019.
Alaaji Mohammed Ajibola Olagbayi to
je alaga fegbe awon agbagba Yewa lo soro yii lakoko ti won se ipade po peluu
awon oniroyin losan yii ni Iwe Iroyin niluu Abeokuta.
O soro yii lati fesi si oro ti won
ni Oloye Olusegun Osoba so pe won ko ti pin ipo gomina si isori kankan ninu
isori metetaa ti won pin ipinle naa si sugbon awon yoo fa eni to kun oju osuwon
jade takoko ba to.
Okunrin to gbenuso fawon egbe agba
ile Yewa so pe latile lawon ti mo Osoba gege bi eni a lo pa ti, won ni se
lo so awon Yewa di ohun alopati ti ko si ye ko ri bee.
Won ni kii se akoko yii to je pe
awon eeyan pataki lawujo bii Oloye Olusegun Obasanjo to je aare tele lorile ede
yii ati Gomina Ibikunle Amosun peluu awon min in ti panupo so pe Yewa ni gomina
odun 2019 kan ni Osoba wa n so iskuso jade pe won ko tii pin ipo gomina si
isori
Gege bi oro ti Oloye Olagbaye se so,
o ni Osoba ko sese maa se iru e, asiko si ti to lati pariwo e faraye nitori o
fee so awon di amunisin.
Okunrin naa so pe ' Lojo kesan osu
kejo odun yii ni Oloye Olusegun Osoba to tun je Araba Yewa soro kan nile e ni
Abeokuta pe won ko tii pin ipo gomina fodun 2019 sibi kankan ati pe eni to ba
wu lati Ijebu le jade sita, ko wa du ipo naa"
O ni oro yii ku die kaato to je pe
akoko tawon ti fimo sokan lati fa gomina kale lati bi ogoji odun le seyin ti
won ti da ipinle naa sile.
Egbe agbalagba ile Yewa ti won je ti
gomina so pe o ti pe die seyin ti Osoba ko ti ro rere ko awon, fun apeere lodun
1992, se ni won lo fa oludije meji kale laarin won lati fi tako Ojogbon Afolabi
Olabimtan ti gbogbo araalu se tie.
Bee naa ni won lo je esu leyin awon
laarin won lodun 1998 si 2003 sugbon ti Olorun gbeja awon ja lodun 2007.
Sibe won ni ko tii deyin leyin awpn
naa, won wa ro lati peluu won nipa ipolongo lati je ki Yewa di gomina. Bakan
naa ni won tun so pe egbe awon nii se peluu oselu.
Olagbaye tun so pe awon gbo pe won
tun ti fee maa lo awon eeyan kan lati fi da aarin won ru, amo Olorun ko ni gba
fun won, Bee ni won ro gbogbo egbe oselu lati rii le won fa oludije gomina won
kale lati Yewa
Sugbon ni bayii, Oloye Kayode
Odunaro to je akowe Iroyin fun Oloye Olusegun Osoba nigba to fi wa nipo gomina
so pe ko si ooto oro ninu ipade tawon agbalagba Yewa naa gbe jade nitori ko
sigba kankan ti Oga oun yii tako Yewa lati ma se di gomina.
Ninu atejade to gbe jade losan yii
lo fi tako ipade tawon eeyan naa se ati pe o lowo oselu ninu. O ni gege bi
enikan to ti sise peluu Osoba, toun si tun sun mo won daadaa, oun nigbagbo pe
awon agbaagba naa si oro toga oun so yii so gbo ati pe ko si ninu awon eeyan ti
won pejo naa ni won beeere oro lowo Osoba nipa erongba e lati je ki Yewa
di gomina fodun 2019.
Odunaro so pe o je iyalenu le ninu
awon ti won pe ara won ni agbagba naa ni won ti ba Osoba sise po ri ti won si
mo bi oro Yewa,
O nI gege bi imo oun,nnkan to je
Oloye Olusegun Osoba lokan ni ki Yewa di gomina lodun 2019 bee lo ni idagbasoke
agbegbe naa tun je lohun.Nitori idi eyi awawi ni oro awon agbagba naa won si
fee fi da wahala sile ni.
No comments:
Post a Comment