Seneto Buruju Kasamu to
n soju ekun Ogun East nile igbimo asofin agba niluu Abuja ti ro egbe oselu PDP
lapapo lati ma se ki gomina tele nipinle Ogun, Otunba Gbenga Daniel di alaga
egbe naa, nitori oun yoo tubo ba egbe naa je ni.
Ninu atejade kan ti Okunrin naa fi
sita lo ti salaye pe oun tako ki Gbenga Daniel di alaga egbe PDP lapapo nitori
ajalu nla ni yoo je, o si tubo le ba nnkan je si ni.
O so pe OGD ko ye lati di ipo kankan
mu ninu egbe oselu naa, depodepo wi pe ko wa a di alaga gbogboogbo fun egbe
oselu PDP naa.
Kasamu so pe ere loun koko ro pe
Otunba Gbenga Daniel n se nigba toun gbo nipa iroyin e to so pe oun fe e dupo
alaga egbe naa, sugbon toun ti wa rii wi pe kii se oro ere rara, o ti koja oju
lasan.
Seneto naa tun so pe "Nigba ti
mo gbo wi pe Daniel fee lo fun ipo alaga egbe, ero okan mi ni wi pe ere lo n
se. Sugbon ni bayii, to ti so ipinu e jade sita lona to ye, maa fi gbogbo enu
so o wi pe Daniel ti mu awada naa koja oju lasan.
"E je ki n so fun un yin pe
Daniel ko ni awon amuye to le fi dari egbe oselu wa.Bee ni ko tun kun oju
osuwon lati de ipo naa rara."
Kasamu tun so siwaju wi pe iro ni
Daniel n pa wi pe oun ti jawe olubori nibi idibo kan to waye.
O ni nigba ti Ojogbon Maurice Iwu si
wa gege bi alaga INEC, eni tawon ti gbagbe nipa e.
"Lodun 2011 ni Daniel kuro ninu
egbe oselu PDP loo sinu egbe oselu PPN ko to tun lo sinu egbe oselu Labour nibi
to ti padanu. Bakan naa lo je pe idibo to sagbateru e pelu adije kan toun naa
wa nile igbimo asofin (House of Representative), Onarebu Ladi Adebutu, ijakule
lo ba pade."
"Nigba ti idibo odun 2015 n bo
ni Daniel sare pada wa sinu egbe oselu PDP. Won fi je olori olupolongo ibo aare
nipinle Ogun, to si kuna koja afenuso latari bi ko se na owo to ye ko na. Oun
si leni to je ki egbe oselu PDP padanu ni South West ati nipinle Ogun.
"Titi di asiko yi ni Daniel ko
ti le e salaye owo to le ni oodunrun milionu (N300,000,000) naira fun ajo
EFCC."
O wa a rawo ebe sawon agbaagba egbe
oselu naa pe ki won ma se sasise lati so pe won fe e yan Daniel lati di alaga
egbe naa nitori pe lakoko to n sejoba nipinle Ogun, opo awon emi lo pa danu,
eyi to je pe titi di asiko yi, ko tii seni to le so bawon odo ileewe fasiti
Olabisi Onabanjo to to ogofa (120) se ku latari wi pe won ja feto won.
No comments:
Post a Comment