Gbajumo olorin Islam ilu mon on ka
ni Alaaji Dokita Abdulkabir Bukola Alayande topo mo si Ere Asalatu ti so pe oun
la ala kan to ya oun lenu, to si ye ki gbogbo omo Nigeria kun fun adura gan.
Gege bo se wi, ninu ala naa loun ti
rii pe Nigeria dabi apadi ti Olorun da to wa ko awon eeyan kan sibe lati maa
fiya je awon eeyan.
O so pe kii se pe oun ro ori oun
tabi gbe agbeleeo jade bi ko se nnkan ti Olorun fi han oun, to si ye ki gbogbo
omo orile ede kun fun adura nla.
Olorin esin Islam naa so pe eni to
ba fee moribo lorile ede yii ni lati di opo Olorun mu,nitori ko si olori kankan
mo, opo ti won roo pe yoo se daadaa ki ara tu araalu lo je pe igi oko lasan ni
won.
O salaye pe bi a ba si ni ka wo
loooto awpn ijoba n fara ni awon araalu pupo, ko si ina, ko si omo bee naa ni
titi ko dara, o ni se ijoba niyen.
Ere Asalatu tun wa so pe"E je
ki n so kinni kan fun yin, ko seni ti oro Nigeria yii ko pa lara, gbogbo awa
osere naa la mo on lara.
Nigba to so nipa irinajo to loo ni
orile ede Cairo, o ni gege bi ise orin to yan layo,awon ko gbodo duro soju kan
lara imo tawon wa kiri lo gbe oun loo, toun si lo akoko naa lati fi sere fawon
ololufe. Ose kan pere lo ni oun lo nibe.
No comments:
Post a Comment