Mi o le gbagbe ojo ifilole kaseeti mi akoko - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 19 October 2017

Mi o le gbagbe ojo ifilole kaseeti mi akoko


Gbajumo olorin Islam nni Hajia Alimot Afolabi tawon oloufe e mo si Ariremako ti so pe ojo manigbagbe lojo toun se kaseeti akoko oun pe akole e ni Ara Ayo je nitori gbogbo owo ti won pa lojo naa lo poora ti won ko si le so bo se rin titi di akoko yii.

Alimot Afolabi, Ariremako
O soro yii lakoko to n ba oniroyin wa soro lori bo se yan ise orin Islam laayo,O so pe gbogbo igba toun ba ranti nnkan to sele nigba naa lo je bi ala loun.

Gege bo se wi, lodun 2007 nigba toun se ifilole kaseeti naa, o ni ka so tododo awon pa owo gidi lojo naa, nitori awon eeyan bii Sefiu Alao, Oloogbe Mugisu Akinpelu, Alaaji Yinka Osikoya, Alaaji Garuba atawon eeyan pataki ni won wa nibe lojo naa.

Sugbon bawon se setan tiny awon dun pe awon ti rowo, awon yoo san awon gbese tawon je lawon ko ba towo, kii se pe awon eeyan jokoo ti, tawon ko ba so pe awon lo gbe owo naa.

O ni oro toun so yii tu egbe ka,ti gbogbo omo egbe fonka sugbon oun dupe pe Olorun tun ti gbakoso, nigba ti olorin Islam naa so nipa bo se bere, O ni " Lanlate ni mo gbe dagba niluu iya mi sugbon omo Igangan ni Baba mi, nigba ti mo wa ni kekere ni mo maa n loo ile kewu,nibe si ni Alfa mi to n ko mi iyen Alfa Iwalesin ti sawari ebun mi."

O ni boun se gba iyonda ni Alfa oun naa ti so foun pe koun tera mo ebun naa,ati pe ni gbogbo akoko awe loun atawon omo egbe oun maa ji were.

Nibe lo ni oun ti pade enikan ti won m pe ni Alaaji Garuba iyen lo so oun deni to n seto lori redio Paramount FM peluu Oloogbe Olu Atoyebi topo mo si Baba Leripa leyin tiyen ku ni aburo e tewo gba, boun sa se bere titi di oni yii niyen.

Bo tile fikun oro e pe opo ipenija loun ti ba pade nidii ise orin naa eyi to ti koko yo ise naa kuro lemi oun, toun si pada sileewe giga polii.

Ariremako tun salaye pe opelope Baba oun kan soso toun ni nidi ise orin Islam iyen Alaaji Abdulkabir Bukola Alayande topo mo si Ere Asalatu lo tun je koun tun pada sidi ise orin Islam naa.

O ni bo tile je pe kaseeti orin kan soso loun ti gbe jade sugbon laipe yii ni tuntun min in tawon ti pari ise lori e  iyen Ariremako yoo jade fawon oloolufe oun.


No comments:

Post a Comment

Pages