Adele giwa fun ileewe giga ti ise
ogbin, Federal University of Agriculture, Abeokuta (FUNAAB), Ojogbon Ololade
Enikuomehin ti je ko di mimo pe o seese ki orileede Naijiria ni atito ati
aniseku ounje, eyi ti yoo po jaburata bi ijoba orileede yi ba se awon nnkan to
ye ki won se, nipa agbekale awon ilana ti yoo mu ki eto ise agbe ati ogbin
dagbasoke.
O so pe pelu awon iwadii toun ti se
atawon nnkan toun ti ri kaakiri, orileede Naijiria kun oju osuwon lati bo ara e
lai je pe won ko ounje wole lati orileede min in.
Enikuomehin, tesiwaju pe nnkan to fa ti
orileede Naijiria ko tii se wa nibi to ye ko wa ni bi awon kudie-kudie ti ko je
ki ise agbe ati ogbin gbooro, iyen nipa bi ijoba se ko lati se awon iwadii
ijinle nipa awon ohun ti yoo mu ki ise agbe dagba soke, ti yoo tun fun won
lanfaani lati wa lara awon orileede to n lewaju nipa tita ounje sawon orileede
kaakiri agbaye.
Adele giwa naa kaniminu pupo lori
akitiyan ati awon ohun amuye ati amusoro ti fasiti naa ni pelu awon imo ijinle
ti won ti se nipa awon nnkan ogin ati eranko, tawon ojogbon si n gbosuba kare
fun won, sugbon ti ijoba ko fun won ni koriya lati je ki awon ise iwadii won yo
sita gbangba, eyi to si n nu ifaseyin ba idagbasoke ounje.
O fi kun oro e pe imo iwadii ijinle
tawon se lo mu kawon se aseyori nipa ise ogbin iresi (rice) ti won poruko e ni
‘FUNAABA 1’ ati ti adie ti won poruko e ni ‘FUNAABA Alpha’, eyi ti won si n
foju sona fun ijoba apapo lati lati wa a bu owo lu, ko si je ko po jaburata
fawon eeyan lati je anfaani e.
Enikuomehin wa gboriyin fun igbese
tuntun ti ijoba apapo sese gbe lati da FUNAAB pada si ileese to n ri sise agbe
lorileede yi, iyen Federal Ministry of Agriculture and Water Resources lati maa
sabojuto awon nnkan ti won n se.
Bee lo rawo ebe sijoba lati yan ajo kan
to n ri soro ise agbe, iyen Agricultural University Coordinating Agency
(AUCA), ti won sese da sile lati rii daju pe won n se awon nnkan koriya fawon
fasiti to n ri soro agbe lorileede yii.
Nigba to n kadi oro e nile pelu ayeye
ikekoo gboye to n bo lona, o so pe awon akekoo 7,677 ti won se Full Time, awon
akekoo 286 ti won se Part Time ni won maa gba iwe eri won lojo naa, nigba ti
awon akekoo 1,442 ti won je akekoo post graduate atawon akekoo 203 ti won ni
first class naa yoo gba iwe eri won bakan naa.
No comments:
Post a Comment