Ajimobi ni Yayi ni yoo di gomina nipinle Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 16 October 2017

Ajimobi ni Yayi ni yoo di gomina nipinle Ogun


Afaimo ni ki wahala maa be sile laarin Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun ati akegbe nipinle Oyo,Abiola Ajimobi lori oro eni ti yoo di gomina lodun 2019.Nitori bi Ajimobi se so pe Yayi ni yoo di gomina lodun 2019

Gomina Ajimobi ati Seneto Yayi
Lopin ose to koja yii ni Gomina Ajimobi so nibi ayeye kan pe Seneto Solomon Olamilekan Adeola topo mo si Yayi ni yoo di gomina nipinle Ogun ninu ibo to n bo.Bo tile je pe inu awon kan ko nii dun si nnkan toun so yii/

Gomina naa tun so pe ko ye kawon tun maa paro fun ara won, nibi toro de yii mo sugbon eni to ba fee binu  lori oro to n so yii ko tete binu.Nitori nnkan tie mi so foun loun so jade.

O so pe “ Lagbara Olorun, bob a di odun 2019, Yayi ni yoo je gomina nipinle Ogun, mo mo pe inu awon kan ko nii dun si nnkan ti mo so jade yii, amo awa ti koja ka ri nnkan ka maa le so jade.

Sugbon a gbo pe latigba ti Ajimobi ti soro naa ni won ni inu Amosun ko dun, ona ti yoo si gba fun akegbe e lesi oro e ni won so pe o n wa kaakiri bayii Sugbon awon to sunmo on so pe  won lo ni ko si nnkan to kan  Ajimobi nipa ibo ipinle oun. Amo,awon omo egbe APC ti so pe yala Amosun fee tabi ko fee Yayi lawon fee fa kale, ibo eleyii yoo koja todun 2015, nitori ko seni to fee loo fenikan ninu egbe naa..

No comments:

Post a Comment

Pages