Yewa kii se eya to kere julo- Yayi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 9 October 2017

Yewa kii se eya to kere julo- Yayi

Oludije fun ipo gomina labe egbe oselu APC to tun je okan lara awon omo ile igbimo asofin niluu Abuja, Seneto Solomon Adeola tinagije e n je Yayi ti so pe Yewa kii se eya to kere julo gege bawon kan se maa n wi pe won ko po, o ni aimokan lo n se iru awon to ba n so bee.

O ni edun okan lo je pe awon aala ti won n pa kaakiri ti je ki iyapa wa laarin awon eeyan lorile ede,  nipinle ati lawon ijoba ibile.

O soro yii lakoko to n se idanilekoo lopin ose to koja nibi apero tawon omo Yewa se niluu London, eyi ti akori e da lori idagbasoke ile  Yewa,
isiro ipa tisejoba n ko.

O ni igbimo ote to n waye lagbaye ti je ki adinku maa de ba awon omo Yewa, topo won si n file won sile nipinle Ogun 

Yayi tun so pe " Bi a ba ka wo opo awon omo Yewa  ni won wa nile Benin,nibi ti Ipokia, Yewa South,Yewa North ati Imeko Afon ti ba won paala po.Bee lawon kan tun ba awon bi ipinle Oyo naa paala. Ewekoro, Ifo ati ijoba ibile Ado Odo Ota tun wonu ara won."
O tun so pe peluu eto ikaniyan to waye lodun 2006,o ni orisirisi lawon abajade ti won gbe jade  nipinle Ogun, eyi to da lori awon Ekun ti won pin in si.
Adeola tun so di mimo pe iha tawon isejoba n ka nipa ipinpo tun je okan lara awon nnkan to mu ifaseyin ba idagbasoke soke ile Yewa,ti ko si ye ko ri bee.
  
O ni idagbasoke to n de ba Ogun East ati Ogun Central ko se leyin awon to ti se gomina lati odo won wa peluu awon ise akanse ti won se sibe.

Nigba to n fi aidunnu e han, Seneto Adeola so pe bi Yewa ko se tii je gomina lati bi odun mejilelogoji seyin je eyi to ba ni lokan je, o ni bi won ba le fun won laye lati di gomima lodun 2019,anfaani nla ni o so pe yoo je ti idagbasoke yoo si de bawon.

 Aare egbe Yewa Descendants Union ti won wa niluu Oyinbo ti won tun sagbateru apero naa so pe akori won lodun yii ni lati so n fawon to wa loke okun pe ki won fowosowopo peluu awon to n sejoba lati wa abayori sawon nnkan to ba n sele.

Lara awon to wa nibe lojo naa Ogbeni Suraj Adekunbi Isola, olori ile igbimo asofin nipinle Ogun, Alaaji Gboyega Nasir  Isiaka, Ojogbon Rahaman Bello, Ojogbon Tope Popoola, Oba Kehinde Olugbenle, olu Ilaro ati Oba ile Yewa atawon min in.
https://ssl.gstatic.com/ui/v1/icons/mail/no_photo.png


No comments:

Post a Comment

Pages