Awon meta daku nibi ayeye igbominira to waye l'Abeokuta - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 5 October 2017

Awon meta daku nibi ayeye igbominira to waye l'Abeokuta

Bi kii ba se opelope Olorun o ku die kawon meta kan gba ibi ayeye odun ketadinlogota ti orile ede yii gbominira to waye niluu Abeokuta de ajule orun,nigba ti won daku lakoko ti ayeye naa n loo lowo.

Ayeye ohun to waye ni papa isere MKO Kuto niluu Abeokuta, lawon eeyan meta naa sadeede subu lule laarin wakati meji ti eto naa fi waye, lara awon to yan bi oloogun lawon eeyan naa.
Okan tie wa lara won to je pe bo ti subu ni eje ti n bere si ni da ni enu e ati imu, eyi to je kawon to n toju alaisan sare sii peluu keke ti won fi maa n wo alaisan.

Keke naa ni won fi gbe loo sibi moto pajawiri won iyen Ambulance, ti won si sare gbe loo si osibitu.
Bakan naa, bi a ba tun ni ka wo, ayajo odun ominira ti won se lodun yii niluu Abeokuta ko dabi bi won se n se tele.

Awon araalu ko fi bee jade sita leyin awon omoleewe, awon eleto aabo ilu,awon egbe to je mo ti Amosun atawon olokada, ko sawon to tun yan bi oloogun.

Ko dabi igba kan to je pe bawon oloja ba se n koja lawon onimoto a tele won, bee lawon elegbejegbe lorisirisii gbogbo won lo maa n tu yeye jade lati ba Gomina to ba wa nijoba sajoyo.

Nigba to tie je pe bi Gomina se de lo ti so fawon eso e pe ki won so fawon to seto pe papapa ni ki won se lojo naa.
Opo awpn araalu ti oniroyin wa ba soro ni won so pe ki ni idunnu elewon won, ti yoo fi kasp bori, se ijoba to n fara ni awon araalu lawon yoo so pe awpn yoo maa tele kaakiri won ladura lawon n gba, ki Olorun tĂȘte gbawon kuro kijoba min in wole.

Amo sa, Gomina Ibikunle Amosun ti ro awon eeyan lati maa lo ayajo ominira lati je ki alaafia joba laarin won. Bee lo so pe gbogbo igba nijoba oun yoo tubo maa se awon ohun amayederun fawon araalu.

No comments:

Post a Comment

Pages