IBB fatileyin e han si OGD lati di alaga PDP lorile ede yii. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 5 October 2017

IBB fatileyin e han si OGD lati di alaga PDP lorile ede yii.




Aare ologun lorile ede yii tele, Ibrahim Badamosi Babangida ti fi atileyin e han si Gomina tele nipinle Ogun, Otunba Gbenga Daniel lati di alaga fegbe oselu PDP lorile ede yii.

O soro yii niluu Minna nipinle Niger lakoko ti OGD atawon iko e loo sabewo sii lojooru Wesde ose yii.
  
O so pe inu oun dun nigba toun gbo pe Daniel fee jade lati dupo fun alaga egbe naa lapapo, nitori Iru awon tawon mo pe o le se ni Okunrin to wa lati ipinle Ogun naa.

O salaye pe bi Gbenga Daniel se fee fara e sile lati sin egbe je erongba to dara lati le je ki egbe naa pada sinu ogo won.

Babangida so pe" Mo mo OGD daadaa, odu lo si je fum mi, inu mi dun nigba ti mo gbo pe o jade lati sin egbe wa, eni ti mo le fowo soya fun un ni, mo fi atileyin mi han si. Daniel alaga mi to n bo lona ,Mo setan lati sise peluu e to ba de be.

Ko to to akoko yii ni Daniel naa ti so pe abewo toun se yii ni lati wa farahan ko si gba iwure lodo Babangida.Leyin naa ni won se ipade bonkele peluu awom to tele Daniel wa ki Babangida.


No comments:

Post a Comment

Pages