Ileese agbejoro kan to n je MJS
Partner ti gbe Ogbeni Dimeji Bankole to je olori ile igbimo asojusofin
tele loo sile ejo giga kan to wa ni Isabo niluu Abeokuta lori pe o kuna lati mu
adehun e se lori owo ise to gba won fun lakoko to n jejoo peluu ajo to n sowo
ilu basubasu iyen EFCC.
Gege bi asoju awon agbejoro naa,
Dokita Yemi Oke se wi ninu ejo kan ti won pe ti nomba e je AB/153/2013 ni
won ti fesun kan olori ile igbimo asojusofin tele naa pe o kuna lati san
milionu lona aadorin naira to je owo ise won sugbon ti won dinku si milionu
meje naira peluu adehun ti won jo se papo
Ninu oro olupejo, iyen Dokita Yemi
Oke loruko ileese agbejoro naa se wi niwaju Adajo M A Dipeolu to n gbejo naa so
pe lodun 2013 ni olujejo tako milionu lona aadorin naa to si sadehun lati san
milionu meje naira sugbon titi di akoko yii ti won ko san owo naa,eyi lo je ki
won tun pada sile ejo
Dokita Oke so pe lati odun 2013 titi di akoko yii iyalenu lo je pe Dimeji Bankole ko ase ile ejo naa se ti ko si je ko ri bee, gege bi eni to mo ofin.
O ni kaka bee se ni o so pe o lo
agbara e lati loo pejo kotemilorun ni Ibadan, sugbon ti won fidi janle
nibe.
Bakan naa lo so pe Dimeji Bankole
funra e lo gbese fawon lakoko tawon EFCC mu to si gba peluu won lati san
milionu lona aadorin naira ti won si gba beeli e.
O tun salaye nile ejo pe leyin ti
won fi sile, ileese agbejoro naa tun bere igbese lati ba gbejo e nile ejo
giga,nigba naa lo fawon ni milionu meta gege bi owo ounje,ileegbe ati moto.
Ninu oro ti agbejoro ti olujejo, Abiodun Aboaba lo ti bebe pe ki won foun lasiko perete lori ejo naa paapaa nipa awon nnkan ti olupejo ro mo ejo.
O so pe
oun sese ri gbogbo awon ti olupejo naa pe, oun si gbodo funra oun laye die lati
ye e wo
Nigba ti Adajo Dipeolu soro o se ikilo pe ile ejo ni faye gba odiwo ka kan lori ejo naa, o wa sun Igbejo siwaju dojo ketadinlogun osu yii.
No comments:
Post a Comment