Bi nnkan se n loo yii afaimo ni ki
wahala maa be nile igbimo asofin tipinle Ogun nitori bi won se lawon asofin kan
se n gbero lati yo olori won iyen Suraj Adekunnbi nipo.
Ohun ta gbo ni pe won ni Okunrin
olori ile igbimo asofin naa ti n fura pe nnkan kan fee sele idi niyii to fi loo
gbe opa ase ile igbimo naa pamo sile ijoba.
Won ni se lokunrin naa loo gbe opa
naa pamo kawon omo ile igbimo asofin naa maa ba dite gbajoba mo on lowo, ko to
di irinajo to loo sese de yii de.
Lose to koja ni Adekunni rin irinajo
loo siluu London nibi apero tawon Yewa sagbekale e yii.Won anfaani naa lawon ti
ko gba ti Okunrin naa fee lo lati fi le kuro nipo sugbon toun naa tete kiyesi
ara.
A gbo pe lati bi osu meloo kan seyin
lawon omo ile igbimo asofin ti pin si meji, metala, metala ni won mu ara won.
Won ni bi Suraj se sunmo Gomina Amosun ju to si n fa akoba fawon ni won se fee
yo ese e lawo.
Iwadii tun fi ye wa pe nitori olori
ile igbimo asofin naa ko fokan tan awon omo abe yii lo mu ti won lo fi loo gbe
opa ase naa pamo sile ijoba.
Sugbon ni bayii, Ogbeni Waheed
Akinola to je oludamoran pataki fun olori ile igbimo asofin naa ti so pe ko si
ooto ninu oro naa pe boya awon kan fee yo oga e tabi pe o gbe opa ase awon
asofin naa pamo sile ijoba.
O ni ko si nnkan to jo pe won gbe opa ase naa kuro
nibi to wa lakoko ti oga loo kopa nibi apero awon omo Yewa to waye niluu
London.
O tun so pe " Titi di akoko ti
mo fi n ba yin soro yii, ibi ti won gbe opa ase si nile igbimo asofin lo wa ko
seni to fowo kan an.
No comments:
Post a Comment