Ebi Odi gbe soosi Ridiimu lo sile ejo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 10 October 2017

Ebi Odi gbe soosi Ridiimu lo sile ejo


Nnkkan ko fi bee rogbo laarin ebi kan ti won pe ni Ebi Odi ati Soosi Ridiimu nitori bawon ebi naa se fesun kana won ara soosi naa pe won gba ile molebi awon lona aito,ti won si n fowo agbara gba won loju.

Sugbon bi a se n ko iroyin yii, ebi naa ti gbe soosi naa loo sile ejo giga to wa ni Isabo niluu Abeokuta, ipinle Ogun,nibi ti won ti n ro adajo to fee gbejo naa lati bawon gba eto awon lowo awon to fee fowo ola gbawon loju naa.

BO SE RI gbo pee bi naa fesun kan Ridiimu pe ona aito ni won ra ile naa ati pe eni ti ko tan mo ebi naa to pe ara e ni Dominic Odi lo tai le naa fun won laije kawon to je ojulowo ebi gbo.

 ileese DOVE QUARRY to je eka to n pawo wole fun Ridiimu ni won fesun naa kan niwaju Onidajo M.O Dipeolu pe won ko ri enikankan ninu molebi won ki won too ra ile lowo Dominic tawon ko mo ri.

A gbo pe ileese kan, TRUST OF D1 QUARRY lawon ebi gbe ile won fun pe ki won maa se abojuto e, ki won si maa se ise won nibe, titi digba tawon yoo fi pinu lati ta a.

Won ni se ni Dominic loo ji ninu ile naa ta fun ileese kan, ti won si fee le awon ti molebi ti fi sori ile naa kuro ni tipatipa. Bee ni won tun so pe won n dunkoko mo won pe ki won kuro ni tipatipa.

A gbo pe ileese Dove Quarry naa ti was pe ejo ti nomba e je AB/280/2017 lati fii tako awon to n ja sile naa pe kileejo da won lowo ko lati ma se yo won lenu titi digba ti won yoo fi pari ejo naa laarin ara won.
Nigba to n sedajo e, Onidajo M.O Dipeolu ti waa pase pe kawon ebi Odi si loo se suuru digba toun yoo fi yanju oro naa, ki won si fi awon to wa lori ile naa sile lati maa ba ise won lo lai di won lowo.

No comments:

Post a Comment

Pages