Awon egbe odo ile Yoruba fatileyin won segbe oselu UPN - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 10 October 2017

Awon egbe odo ile Yoruba fatileyin won segbe oselu UPN

Ogunsiji Azeez Micheal

Awon egbe odo kan nile Yoruba lawon ti setan lati sise po peluu egbe oselu UPN fun ti ibo to n bo lodun 2019. 

Bakan naa ni won lawon setan lati kopa to joju lati dije fawon ipo to se pataki nibi ibo to n bo naa.

Atejade yii jade nibi ipada tawon odo naa se niluu Eko eyi ti eni to je alakoso fegbe awon odo naa to tun je aare egbe fegbe awon odo lorile ede yii iyen YYCN, Ogbeni Oluwole Eric gbe jade lakoko ti won ba oniroyin soro.

O ni ipinnu tawon fi gbe akori pe egbe odo fee gba ile igbimo asofin ni lati koja ija sawon ipenija to ti wa nile nidi oselu ati lati satunse eto oselu nile  Nigeria.

Aare egbe naa tun so pe awon pinnu lati sise po peluu egbe oselu UPN, nitori awon gba gege bi egbe oselu to ni nnkan se peluu awon odo.

Ati pe ilana ti Oloye Obafemi Awolowo fi sile ninu egbe naa lakoko to koko da sile,si wa sibe,tawon to wa nibe ni ipinnu lati maa tele.

Awon nii eto eko ofe, ilera ofe,ipese ise fawon ti ko nise,ati idagbasoke lawujo. Bakan naa lo tun gboriyin fawon omo ile igbimo asofin niluu Abuja lori awon abadofin tuntun ti won sese gba wole,eyi to ni se peluu awon odo.

Lara awon to tun soro nibi ipade oniroyin naa ni Otunba Soji Adeyemi ninu oro e lo ti bu enu ate lu awon oloselu orile ede yii fun bi won ko se faye gba awon odo lati kopa to joju,eyi to si n mu ifaseyin ba eto oselu wa.

O so pe ise pupo lo wa niwaju awon odo ti won ba setan lati gbakoso oselu lowo awon ti won korin bamu bamu lawon yo, awon ko mo pe ebi n pa omo enikan.

Gbogbo ara lo ni awon odo fee fi satileyin ati ifowosopo peluu egbe oselu UPN lorile ede yii, bee lo tun lawon ti seleri lati sise po peluu odo to ba nifee lati dije fun ipo ninu IBO odun 2019.

Nigba toun soro nibe,alaga fegbe oselu UPN lorile ede yii, Ojogbon Bankole Okuwa gboriyin fawon odo fun igbagbo ti won ni si egbe oselu naa lati bawon sise po.

O wa seleri lati gbakoso egbe naa le won lowo niwongba ti won ba pinnu lati sakoso e lorile ede yii.

O wa kede pe ofe lawon odo to ba wa labe egbe odo fee gbakoso ile igbimo asofin yoo gba tikeeti ti won ba fee dije fun ibo to n bo yii.

No comments:

Post a Comment

Pages