Ko seni
to gbo nipa Okunrin kan ti won n pe ni Omooba Olatunde Rotimi Paseda tele lagbo
oselu, nitori eni ti Olorun bunkun fun to si koju mo okoowo e ni.
Sugbon
lodun 2014 ni okiki e bere si nii yo nigba ti egbe oselu UPN faa kale
gege bi oludije fun ipo gomina to waye lodun 2015, latigba naa lo ti n da bi
edun, ti ko fa seyin.
Bo tile
je pe Okunrin naa fidi remi nibi ibo to waye , ipo keta lo se sugbon iyen ko
nii ko fa seyin tabi da omi tutu sii lokan, titi di akoko ti a n ko Iroyin yii
lowo opo awon eeyan lo ti pase Okunrin naa doloorire.
Gbogbo
igba tawon oniroyin tabi awon araalu ba n ba soro, ohun kan to maa n jade lenu
e ni oun ko fee je ki ilana ti Oloye Obafemi Awolowo fi sile baje, oun lo si je
pataki foun lati tele.
Lojo
kejilelogun osu kefa odun 1965 ni won bi Olatunde Rotimi Paseda niluu Eko,Awon
obi e Ogbeni Olaitan ati Arabinrin Victoria Paseda ni idile oba Ramuja,ti won
dade Adeneye ni Omu ijebu nijoba ibile Odogbolu nipinle Ogun.
Rotimi
Paseda tawon eeyan tun mo si omo iya Tisa loo sileewe girama Baptist
Academy, to wa ni Obanikoro niluu Eko nibe lo ti se idanwo oniwe mewaa.
Bo se
setan lo fi orile ede yii sile loo si oke okun nibi to ti loo tesiwaju ninu eko
e. Ngba to ko eko nipa isakososo oko iyen Transport Management iyen lodun 1988
bee lo tun kawe gboye imo ijinle lori isakoso irinajo igbafe iyen ni yunifasiti
Cardiff, Wales, UK.
Omooba
Rotimi Paseda tun je omo egbe fun ile eko to n ko nipa oko nile America, to si
tun sise die peluu awon oyinbo ni European Air Tour Operator peluu Euro Skyhop
International ko to wa da tie to pe ni Skylink Travels and Tours sile ni
nnkan bi odun meedogbon seyin .
Paseda ti
kuro ninu omo ti ro pla ri nitori ileese nla merin lo ni ni Oke Okunrin, bakan
naa lo tun da awon ileese nla ti ko niye sile lorile ede yii,nibi ti opo
awon eeyan ti n je labe e.
Laipe yii
ni won daruko e mo awon bii Oloye Olusegun Obasanjo ati Oloye Olusegun Osoba
lara awon omo ipinle Ogun Olorun un ti won se daadaa julo,ti won si ti fowo won
gbe nnkan ribiribi se lagbaye.
Bee lo
tun da ajo kan sile eyi ti won pe ni Paseda Legacy Foundation nibi ti won ti
ran opo awom araalu lowo laifi ti oselu se, o le ni egberun merin obinrin ti
won janfaani eyawo lati fi dokoowo sile labe ajo yii.
Ka ma ti
wa so opo awon ti ara won ko ya ti won ti so ireti nu ti Okunrin yii labe ajo
naa ti gbowo kale lati gba emi won la.
Akiyesi ti
a se peluu Okunrin naa ni pe ko tii je ki ipo Gomina to n du te e lowo to fi
bere awon eto idanwo fawon eeyan. Ko fi ife to ni si eto eko fale rara, idi
niyii to fi je pe bina eto eko se n jo loo ni ajoreyin se n dun.
Ninu
isinmi tawon omoleewe gba koja yii awon bii egberun meje omoleewe lati
alakobere titi de girama ni won janfaani eko ofe kaakiri ipinle Ogun.
Idi niyii
tawon to sunmo okunrin yii fi so pe akanda eda ti Olorun fee lo fun ipinle Ogun
ni Paseda ti won ba le fun in laye lati di gomina ninu IBO to n bo lodun 2019
labe egbe oselu
UPN.
Oun gan
tie so pe oun nigbagba ninu itesiwaju laifi toro osele se nitori iyen lo le mu
idagbasoke ba iluu ati ipinle lapapo.
O ni ko
si nnkan to buru ju ki ijoba tuntun min in ba te siwaju ninu ise akanse tijoba
to ko gba wole ko ba le pari lakoko e.
O so pe
bawon to ba wa nijoba ba se daadaa bi komisanna, ko si nnkan to buru lati bawon
sise po tabi sise po peluu nigba to je pe idagbasoke ilu ni gbogbo won n ja fun.
Eyi to wa
tun se panbanbari ni pe ko si eya ti ko feran Okunrin yii bawon Hausa se n se
dansaki fun in bee lawon ibo naa so pe akoni eda ni.
Ko le ya
wa lenu bi won ba lawon eya mejeeji yii foye da lola ti won si so pe asoju omo
Yoruba rere ni nibi gbogbo.
No comments:
Post a Comment