Awon araalu Ijemo gboriyin fun Oga Olopaa DPO Oke Itoku - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 5 October 2017

Awon araalu Ijemo gboriyin fun Oga Olopaa DPO Oke Itoku



 Ogbeni, Musiliu Ishola Doga, DPO Oke itoku



Awon araalu Ijemo atawon agbegbe e ni Abeokuta ti gboriyin fun Ogbeni Musiliu Ishola Doga to je oga olopaa,iyen DPO Oke Itoku ni Abeokuta fawon ise takuntakun ti won lo ti se lati bi osu mokanla seyin to ti de ilu naa,eyi to je kawon odaran dinku lawon agbegbe naa.

Gege bi a se gbo, iberubojo lo maa n je fawon araalu naa lati gba iwaju tesan naa koja nitori awon iwa aito ti won lawon olopaa maa hu sawon araalu nigba naa.

Won ni opo igba lo je pe ateni to wa fejo sun atawon ti won pe lejoo lo je won maa n faragba,iberu ni ko si n je kawon araalu loo fejo sun..

Sugbon bi won lo se de lo ti koko je ki igbora eni ye wa laarin awon araalu ati olopaa nitori ore lawon je si ara won.

Iyalenu lo si je pe gbogbo awon odaran ti won fara pamo sawon agbegbe naa lo ti koko sise le lori, eyi to je ki awon afurasi naa sa kuro ni Ijemo.

Bee lawon araalu tun so pe ko si nnkan to n je ole, tabi ajinigbe peluu omo egbe okunkun mo niluu naa, idi niyii ti won fi kan sara si won.

Ninu oro  Ogbeni Femi Adegoke to je alaga fegbe PCRC ti ekun Oke itoku, o so pe latigba tawon ti n ni DPO lagbegbe naa ti okunrin ti won n pe ni Musiliu Dogs yato,nitori opo awon atunse lo ti se,eyi tawon to wa nibe tele kuna lati se.

Bee lo so pe ko foro awon PCRC iyen egbe to n ri si ibasepo laarin olopaa atawon araalu sere,ko si n figba kan bokan ninu latigba to ti de bee

Adegoke tawon eeyan tun mo si Baba Seun tun so pe oun ko le ka aimoye ise aseyori ti DPO naa ti se fun bi osu mewaa to ti wa nibe.  O ni ko sejo ti won gbe loo sodo e to fi fale, loju ese ni yoo ti gbe igbese le lori.

Panbabari e ni to tun jo awon olopaa abe e loju gege bi a se gbo ni pe bo se de ofiisi e tuntun yii lo ti fowo ara e tun ofiisi naa se, eyi to mu kawon araalu to ri naa dide iranlowo.

Ogbeni Remi Lawal toun naa je okan lara awon to ni ofiisi lagbegbe naa so pe peluu gbogbo nnkan ti okunrin naa ti se fawon lenu igba to de, awokose rere lo je fawon, nitori ifokanbale ti de bawon.



No comments:

Post a Comment

Pages