Egbe Accord lawon setan lati gba ijoba nipinle Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 25 August 2017

Egbe Accord lawon setan lati gba ijoba nipinle Ogun

Egbe oselu Accord nipinle Ogun ti paroko ranse segbe oselu APC pe ki won maa pale eru won mo nile ijoba nitori awon ti setan lati fi igbale won gba won danu ninu ninu ibo to n bo lodun 2019.

Asoju Oba Michael Adesanya to je okan lara igbimo fegbe naa to tun je olupolongo lo soro yii lakoko to n ba oniroyin wa soro ni ofiisi egbe won to wa ni Ita Oshin niluu Abeokuta.

O so pe kii se pe awon sese da egbe naa sile, o ti wa kaakiri orile ede yii, o kan je pe ipinle Oyo ni won ti n polongo e ju ni amo ni bayii awon ti fi gbogbo ara duro nipinle Ogun lati gbajoba lowo APC.

Oloye Adesanya tun so pe egbe Accord je egbe omoluabi, nitori gbogbo awon to wa nibe loro araalu je logun,ati pe o je egbe to fee je ki iderun de ba gbogbo omo ipinle Ogun.

O tun so pe bo tile je pe egbe meji ni okiki won kan lorile ede yii iyen APC ati PDP, ohun to si n fa ni pe owo ti won n ri ko je lo je kawon eeyan mo won.

Sugbon ni ti Accord o lawon tawon roo pe awon ko ni abawon lara lawon ko ara won sinu egbe naa nipinle Ogun.

Adesanya ni gbogbo awpn ni Pataki nitori ibo kan le gbeeyan subu sugbon eni to je olori awon nipinle naa ni Dokita Doyin Okupe, nigba ti alakoso awon je Alagba Isiaka Amusa. O tun fi kun oro e pe awon eeyan daadaa to wa ni APC, PDP ati UPN ni won ti wa darapo mo egbe Accord.

Nigba to n so nipa nnkan ti egbe naa ni fun ipinle Ogun, Okunrin naa so pe lakoko naa nnkan ti egbe awon duro lori ni iderun,fun gbogbo eni to ba ti je mekunnu. Boya nipa eto eko, ilera, ogbin atawon nnkan min in.

O so siwaju pe ko si ona to dara nipinle Ogun leyin Abeokuta to je oluulu nipinle naa, o ni bawon eeyan ba loo sigboro kaakiri yoo ri pe se lawon ona yii fojoojumo baje.

Asojuoba ni " Ebi  n pa awon eeyan,ijoba ibile to ye ko sunmo araalu, won ti pare, won ko le se nnkankan,gbogbo e lawa maa se, ta maa ji won pada ti won yoo si pada bo sipo."

Bakan naa lo tun so pe eto eko tun je awon lohun tawon ba dejoba.Okunrin yii wa gba awon araalu nimoran lati rii pe won fowosowopo peluu egbe Accord nitori awon nikan lo le mu iderun wa awon yato sawon to n fenu se.

No comments:

Post a Comment

Pages