Kii se tuntun mo pe
wahala kekere ko lo m sele ninu egbe PDP nipinle Ogun, oro won ti di egbinrin
ote to je pe bi won se n pa kan ni omin in tun bere. Lojo Isegun ni Adebayo
Dayo ni alaga egbe naa ba BO SE RI soro lori awon awuyewuye naa,ati bi won se
gbe Markafi ati igbimo fidihe loo sile ejo. Boro naa se loo niyi.
Oruko mi ni Oloye
Adebayo Dayo, Akogun Ijapara ni Ijebu Igbo, alaga egbe oselu PDP nipinle Ogun
lodun 2012 di akoko yii, mo ti koko je alaga egbe naa laarin 2012 si 2016, ko
to di pe won tun dibo yan mi leekeji. Nitori ofin egbe wa gba wa laye pe eni to
ba se alaga lakoko tun le se e ni eleekeji, nitori idi eyi eleekeji ni mo n lo loo yi.
Bi
irinajo naa se bere
E je ki a tan imole
si ko yee yin daadaa, nigba ti mo n se alaga loo, won kowe si wa lati Abuja pe
ki alaga kookan wa ra foomu, eyi ti won yoo fi dije fun ipo, mo loo si
Abuja, mi san milionu mesan naira ati egberun din die legberin
naira,(9,762,000milionu naira) fawon to fee dije nipinle Ogun, mo si tun ra
kaadi egberun mewaa tiye e je milionu meji abo naira, mo ko wa sipinle Ogun.
Sugbon ko to to yen,
awon kan ti won wa ninu egbe Labour Party, Otunba Gbenga Daniel pelu Ladi
Adebutu, ninu osu kokanla odun 2014 ni won wa darapo mo egbe PDP, ti mo si loo
si Abuja ni eemeta lati gba foomu ti won yoo fi foju fo won da lati dije iyen Waiver,
ki won le kopa lati dije.
Nitori egbe PDP so
pe eni ti ko ba ti lo odun meji ninu egbe ko le gbe apoti pe oun fee se
ohunkohun, a fi ti won ba foju fo won. Egbe lapapo lo si le se , emi ni mo ko
iwe won loo si Abuja.
Eemeta ototo ni mo
loo si Abuja nitori ki won le dije. Bi kii ba se bee ni 2016 ni won ko ba letoo
lati dije. Ko seni to fun mi ni kobo ninu won, ofe ni mo loo se, gbogbo owo ta
n soro e, pe a gba foomu a n se gbogbo e, enikan soso, Buruji Kashamu, oun
nikan lo n nawo egbe, to si gbo bukata e.
Bi won se gba foomu
lodo wa ti Ladi omo Adebutu wole gege bi asojusofin, eni ti ko tii letoo lati
so pe ohun fee gbapoti kan, bo se wole, lo ti yara e soto pe gomina loun fee
se.
A si mo pe Gbenga
Daniel, Remo lo soju fun, to fi wole gomina fodun mejo, bawo ni elomin in yoo
tun se wa dije pe oun fee se gomina lati Remo, nigba ti kii sawon nikan lo wa
nipinle Ogun.
Sugbon owo oojo, owo
omo alaigboran ti won n ri lojoojumo, ninu awon to n ta tete, owo yen lo n ti
won, pe awon fee se gomina lati Remo. Oro
e bi ti Yayi to loun fee wa se gomina nipinle Ogun, to si n se Senato fun Eko
lowolowo, ibo ti won si di ni osu to koja ni Ekoo Yayi loo dibo nibe.
Iru e ni Ladi
Adebutu fee se to mo pe Remo ti se odun mejo. Nigba ti oro ipade gbogbogbo iyen
congress bo, Ladi loo si Abuja, o loun naa fee ra foomu, won wa beere lowo e pe
bawo lo se fee ra, se oun ni alaga egbe nipinle Ogun ni, won ni to ba fee ra
foomu ko pada si ipinle e.
Ladi Adebutu atawon
omo eyin e ko ra foomu, se ni won lo te todo ti won ni. nigba ta n se congress
mo ko si iwe iroyin kii se pe a yoo se,
o si loo ni alaafia. Awon Ladi ko wa, won ko si gba foomu, gbogbo awon
agbofinro lo wa nibe.
Nigba tawon kan
pariwo pe awon lawon ni alaga, a loo si kootu pe ki won gba wa lowo awon eeyan
ti won dibo leyin ta wole. Kootu ye iwe wo, won la wa la ni Oloye egbe ipinle
Ogun titi di 2020 bi oro se loo niyen, latigba naa won gbokiti.
Nitori baba Ladi ra
oteeli si Abeokuta, ibe ni won fi se sekiteriati, ibe ni won lo jokoo si, ti
won ko obinrin, ti won si n muti, apeje ni won se be, kii se oselu. Nigba ti egbe
pin meji ni Abuja, won loo si egbe kan, emi si ree alaga PDP ni mi, mi o ni da
apa kan si fi apa kan sile, Markafi pe ipade ni Abuja mo loo sibe, nigba ti
wahala naa po, mo loo sibe, Shefiu naa pe ipade tie ti mo n loo, awon mejeeji
ni mo gba ni temi o.
Sugbon awon gba pe
Markafi ni tawon to ba ti de be, o maa se tawon, nigba tile ejo giga julo si so
pe Markafi lawon gba, mo ni lati ko leta fi kii ku oriire, a si n ba aniyan
loo.
Se ni won wa loo lo
ese lodo Markafi, a si ti n loo si ipade nile egbe wa ni abuja, ohun lo ga ju
lo ayafi ipade gbogbogbo iyen konfesan lo tun fee ju lo. Nibe ni won ti so pe
ipade ta ti se ka to loo si Port Harcourt lawon gba wole, pe gbogbo won lo
yege, a fi awon ipinle mefa ti won ko tii se ti won, pe awon lo maa se.
Afigba ti won so pe
won fee pe ipade gbogboogbo min in ta si loo sipade nibe, ti enikan si so pe awon
fee ki won bawon gbe Sikiru Ogundele sipinle Ogun, nigba ti ariyanjiyan won ko mo nnkan ti won n se, won wa lawon tu
oloye ipinle Ogun ka. Awon ti gbagbe pe ofin to gbe awon dori aleefa, ti won fa
lati ile ejo giga loo si ko te mi lorun titi de eji to g ju lo patapata, ko to
fidi won mule, ojo naa ni Sherif ti ko eru e kuro ni ofiisi egbe wa.
Ofin naa a lo gbe
awa naa duro nipinle Ogun, idajo ta gba, gbogbo e lo wa lowo wa, ko si seni to
pe ejo kotemilorun lori e, ejo naa la duro le lori.ojobo ti ipade ti won se
gbeyin yi ku otunla la tun lo gba ase min in ni kootu pe won ko gbodo so pe ka
maa wa sibe, atawon asoju won, gbogbo e ni won gbo. A fi bi won se so pe awon
tu egbe ka, a si kowe si won pe ori ere igi leyi ti won se yen.
Nitori e, ofin to
gbeyin duro gege bi alaga, ohun lo gbe awa naa duro nipinle Ogun. Bi a ba si
loo si kootu kotemilorun to so pe a ko lagbara lati wa nibe, ojo naa la maa ko
eru wa. Sugbon owo ti a wa yii, bi e ba yan awon oloye fidihe, ko le seese o,
nitori awa la wa nibe o.
Muazu lo je gege bi
alaga lapapo, to seto ipade gbogbogbo ta se ti mo si wole leekeji, nigba ti
Muazu kuro nibe leyin ibo, ni igbakeji e gbakoso ti won so pe won ti gbe ipo
alaga egbe PDP wa si North, won ni awon ni won yoo fa alaga sile.
Awa loo si Abuja, awa alaga pe ipade si ago mejila, ipade yen la
n se loo ti Ayodele Fayose peluu Wike ati Mimiko peluu awon gomina meji mi in,
won ka ni ka jo o, awon gbe enikan bo, latise alaga, eni naa lowo lowo, o si ti
se gomina ati senato ri, iyen Ali Modu Sherif .
Alaga Borno dide pe awon
ko le gba pe Sherif to sese darapo mo egbe ko di alaga, won lawon ko le gba,
nitori awon mo daadaa. Gbogbo alaga so pe oro le gbo bii Ayo Fayose se n be wa niyen, nigba ti ebe si
po la bere si ni be alaga Borno pe ko gboro si lenu, nigba ta de isale, awon
BOT so pe awon naa ko gba ti Sherif, awa alaga la si poju nigba ta be awon naa
ni won gboro si wa lenu, Ayo Fayose lo mu Sherif wa o.
Nigba to ba si mu
eeyan wa, ta gba towo tese, to wa de aarin meji to so pe o se tie mo, bi emi se
wa yii, a jo daa PDP sile ni, emi ni mo koko gba alaga egbe nigba ijoba ibile
wa ni Ijebu Igbo, won so nigba naa pe egbe Hausa, awon ko se, emi ko boju weyin
o, mi o loo segbe mi.
Gbenga Daniel, AD lo ti wa, awa la gba segbe.
Gbogbo won lo wa pe ara won ni olori egbe bayii, nigba ti won ba ti rowo ji
nijoba, won a so pe awon ti di olori. Se ni ki eeyin oniwe
iroyin gbe wa lowo awon to n rowo ijoba ji, ti won so ara won di asaaju
apapandodo, awon ni OGD atawon min in. nigba ti OGD binu 2011 pe won ko je ko
fa gomina sile, lo loo darapo mo PPN, nigba to se tiko muna doko lo loo si
Labour Party, leyin naa lo pada wa si PDP, emi ti mo loo gba waiver fun
ni yii, nitori o gba foomu pe o fee loo fun Senato, ki Buruji to na o.
Bi
isokan yoo se joba ninu egbe ni mo fee se tele
Nnkan temi fee se
tele ti ko ba se rogbodiyan tawon omo egbe ti won wa lodo Ladi Adebutu, ti won
fowo tete da egbe ru ni pe, kii pe awon agba egbe bii marun un si koro inu
yara, ki n si be won pe eleyii ko se da se, bi kii se kaa di okan, ko danmoran nipinle Ogun. Ohun ti mo fee se ni
pe ki n pe awon Dimeji Bankole, OGD, Ladi Adebutu to n fowo da gbogbo e ru, ka
pe Buruji Kashamu to je olori wa, ka be won, leyin naa ka bere ajosepo to
danmoran.
Idi
tawon kan fi gba Mega Party loo
Eni to ba wa nibi
kan tawon kan fee fi owo ola gba loju, ti ko si ye ko ribe, Aimoye igba ni
Omisore jade ni Osun to loun fee se gomina, ti ko seesee, nitori Olorun
ko fowo sii. Sugbon ni Osun to so ara e di igbakeji orisa pe oun ni Olorun won,
ipade NEC ta se, bi won se gba ti wa wole ni won gba ti Osun naa wole, sugbon
ti ko te Omisore lorun, se e mo pe awon to wa ni Abuja ko mo pe awon Omisore ko
je nnkan kan nile, won ko le gbapoti kanselo ki won wole, sugbon nigba ti won
ti ri won peluu ibo ti won wa ni won fi gboro si won lenu, ohun lo da awuyewuye
sile.
Nigba ti won ba si
rip e orogun iya won ji oun jo lo, o gbodo wa ona abayo idi niyii tawon eeyan
fi loo si mega Party o. Egbe naa si ti gbayi yi gan ni Ekiti, Osun, ohun to le
fa ti egbe naa ko fi ni gbayi mo ni ki awon PDP sootito, ti won ba so tito,
gbogbo awon to lo si mega party la maa ba soro, sugbon lai ba won soro, ewu n
be loko longe.
Emi
ni mo mu Ayo Fayose mo Buruji
Ayo Fayose to loo
kaakiri asiri ti tu, a ti ri furo adie, ogbologbo ole ni, nitori nigba tijoba
lo wo akanti e, aimoye milionu ni won ba nibe o. emi ti mo mu Ayo Fayose mo
Buruji ree lojo to wa si Abuja, a ko mo ri, a kan maa n gboruko e ni, nigba to
si wa ba wa, o ni e joo, eni ti won pe ni Buruji loun wa, o ni, se a mo oun ni,
o so pe oun ni Ayodele Fayose, a ba ni ko jokoo.
A wonu yara loo, a
lo ba olori wa Kashamu lori bedi e, pata nikan lo wa nidi e, pe enikan to je
Fayose loun fee ri yin. Won ni ko wole, nigba to si wole la wa kuro nibe, nigba
to maa jade bayii, omi n bo loju e, o ni Abuja toun wa yii, oun ko rowo ra
first class tikeeti, pe Economi loun ba de bi, o loun ko reeyan bi tie ri, o lo
foun ni 20,000dollars pe koun loo maa fi ba ise loo.
Bi Buruji se bere to
gbase Fayose se niyen, Aimoye je tirela iresi, kerosini ta gbe loo si Ekiti fun
ipolongo ibo awa o le so pe iye bayii ni okunrin naa na lori Fayose. Bi o se
dori oye, ti agbara te lowo si e, lo gba pe oun ni igbakeji Olorun le won lori,
iyen lo fa ti mega party fi gbale ni Ekiti, kawon Markafi ya mo ise ti won
yoo se, Ki gbogbo awon to loo le pada saye won.
Emi
ko le kuro ninu PDP
Oro temi yato si ti
gbogbo won, nibo lemi n loo, nigba ti mo maa rale ile akoko laye, 1974 ni, ni
England omo odun mokandinlogbon ni mi, kii se agbara mi ni mo fi wa nibi, odun
mejilelaadorin ni mo pe lodun yii, nibo ni mo n loo, awon jegudu jera ni won
maa so pe orun igi laparo ku si.
Gbogbo omo mi pata
ni mo ti so pe mi o gbodo ri won ninu oselu, emi ti mo ti rari si, to ba di
odun meji si akoko yii, no no maa fi sile patapata, ibikibi to wa ko ja si,
leyin naa ni mo tun ba eeyan jade mo fun oselu, emi o loo sibi kankan.
Ko
seni to le da mi duro ninu egbe
Kin ni esun naa ti
won so fun yin pe a se, se a loo si APC tabi akoko pe, Buruji lo sanwo egbe. Fun
odun mejo ti OGD fi se ijoba egberun lona aadota naira lo fun wa, gbogbo won ko
de Sekiteriati fodun merin, won ko wa si ipinle Ogun. Agbara wo ni won ni lati
fi da wa duro, Markafi gan ko ni ase lati so pe oun da senato duro, ko si eni
to le fiya je wa, a fi NEC, bawo ni Gbenga Daniel atawon Ladi ti mo fun ni
tikeeti so pe oun maa da seria a fun mi.
No comments:
Post a Comment