Awon omo eyin Osoba ti Yayi fehonu won han lori Ibo egbe APC - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 2 August 2017

Awon omo eyin Osoba ti Yayi fehonu won han lori Ibo egbe APC

Ese o gbero ni ogba Bode Mustapha to wa ni Leme niluu Abeokuta losan an oni in Wesde ojooru nigba tawon omo egbe oselu APC ti won je omoleyin, Oloye Olusegun Osoba ti won sise fun Yayi lati di gomina fodun 2019 pejo nibi ti won ti fi ehonu won han lori ipade gbogbogbo egbe naa ti won ti yan awon oloye egbe fawon ijoba ibile.

Gege bi BO SE RI se gbo, latigba ti ibo naa ti waye lawon omo egbe naa ti binu lori ona ti won ni Gomina Ibikunle Amosun atawon eeyan e gba lati seto naa, ti won si so pe won tun fee fi da wahala sile ni sugbon awon ko nii gba fun won.

Nibi ehonu to waye naa ni Onarebu Kunle Adesina to je alaga fun egbe naa ni ni ekun Ogun Central fegbe oselu APC ti kesi awon oloye egbe naa lapapo lati fagile ibo naa, nitori ona modaru ati magomago lo so pe won seto ibo naa.

Okunrin naa fesun kan eni to je adele alaga fegbe oselu APC iyen Tajudeen Ilemboye lori bo se yo oruko awon asoju atawon oloye egbe kan kuro fun eto naa, eyi ti won lo tako abala ofin egbe naa Article 21D9(V1). O ni se ni alaga naa ati oga e to n sanwo fun tun ko lati kopa nibi ibo ojo naa.

Adesina loun wa ro awon igbimo ti won ni won yan lati seto ibo naa lapapo ninu egbe APC lati ma se gba abajade esi ibo naa wole rara,ki won si fagile.

O wa so di mimo pe ehonui tawon se yii, o wa ni ibamu ati ofin egbe naa ati pe gbogbo awon tawon jokoo naa kii se oni jagidijagan oloselu, awon ko si le da alaafia ilu ru, idi niyii tawon fi gbe igbese tawon gbe naa.

Ninu oro ti Tunji Egbetokun to ti figba kan je olori nile igbimo asofin nipinle Ogun nibi ehonu naa lo ti awon gbe igbese naa nitori awon ko fee kawon kan maa tabuku Oloye Olusegun Osoba.

O ni lojumo to mo loni in Segun Osoba lawon mo gege bi olori ati adari egbe naa nipinle Ogun, nitori idi eyi lawon se ke gbajare, o ni ki won mo pe boya nnkan ti won se ti won mu je lodun 2014 si 15, o  ni won ko le ri mu je lakoko yii.

O ni arun to seni leekan ni ko tun gbodo se ni mo, nitori gbogbo ona lawon yoo gba lati ja ajaborio. O wa pari oro e pe lakoko yii, ko seni ti yoo fegbe sile fun Amosun atawon eeyan e.

Leyin ipade oniroyin naa lawon omo eyin Seneto Olalekan Adeola topo mo si Yayi wa gbe orisirisii kaadi jade nibi ti awon akole po lorisirisi ti won so pe magomago nibo ijoba ibile egbe naa to waye lojo kokandinlogbon osu yii.


Jakejado ipinle Ogun lawon asoju ti won je omo leyin ati oloye egbe APC ti wa sibi ehonu naa.

No comments:

Post a Comment

Pages