Lose to koja lawon kan ko ara won jo ladugbo Isale
Abetu niluu Abeokuta, ko si si nnkan min in,won jo forikori lati wa ona ti
abayori yoo se maa de ba opo awon ipenija topo awon eeyan n koju ninu aye yii.
Wrench Adeyanju |
Nigba ti Olorun yoo si ba won fase si, won pamopo won
si da egbe kan tuntun sile ti oruko e n je WRENCH CLUB. Bo tile je pe won ko ti
se ifilole egbe naa sugbon o seese ko je pe ojo Eti Fraide ose yii ni won yoo
se ni Ooteli FIKAZ to wa ni Isale Abetu bere lati aago meje ale.
Gege bi a se gbo, lojo naa lawon omo egbe yii atawon
tuntun yoo jo fimo sokan lati pa ero po lori bi igbega ati idagbasoke yoo se de
ba egbe naa.
Iwadii fi ye wa pe opo awon eeyan jakanjakan lawujo ni won ti fi ife won han lati darapo mo egbe naa.
Iwadii fi ye wa pe opo awon eeyan jakanjakan lawujo ni won ti fi ife won han lati darapo mo egbe naa.
Lara awon ti won wa ninu egbe naa ni Adeyanju
Adebowale ti won je alakoso egbe naa, Ajibode Ibunkunolu topo mo si
Blesodec, Odeyemi Abiodun Samuel, Abiodun Muibi, Kayode Falola, Kasali
Temitayo, Johnson Akinpelu, Kayode Ogunnaike topo mo si Sir K atawon eeyan pataki
min in ti oruko won ko ti te wa lowo.
BO SE RI tun gbo pe awon ti egbe yii wa fun lawon timo
ati ero won yoo jo maa papo lati jo maa doju ko ipenija to ba n koju ipinle
Ogun, bee ni kii se fun oselu,tabi ibi tawon kan yoo fee lo lati maa loo awon
eeyan nilokulo.
A tun gbo pe WRENCH tun wa fun lati maa ran omo egbe
lowo,lati jo maa gbaruku ti ara won, bee ni won yoo si tun maa seto idanilekoo
loorekoore fawon eeyan nipa ni nnkan ba se n loo si ni awujo.
Ogbeni Odeyemi Abiodun Samuel lo fee gba awon omo egbe
lalejo nibi ayeye ifilole egbe naa to fee waye lojo Fraide ose yii, oun naa si
ti seleri pe oun ti murasile fun ayeye nla to fee waye lojo naa.
Bee ni Ogbeni Adeyanju Adebowale to je alakoso fun
WRENCH CLUB tun so pe aye si wa feni to ba fee darapo mo egbe yii leyin ti won
ba fi lole lojo naa,nitori gbogbo wa ni ojo iwaju ipinle Ogun ati orile ede yii
kan.
No comments:
Post a Comment