Enu o gba iroyin ni ojooru Wesde ana ni Omu Ijebu nipinle Ogun nigba tawon eeyan tu yaya sita lati ki banki tuntun to sese wolu naa iyen Heritage kaabo siluu naa.
Gege bi a se gbo, Omooba Rotimi Paseda
to je oludije fun ipo gomina labe egbe oselu UPN lo sagbateru bi banki tuntun
naa se woluu,eyi to je ki inu awon araalu naa maa dun.
Arabinrin Olayemi Layeni lakoko to gba iwe eri |
Iwadii fi ye wa pe edun okan lo je fun
won niluu naa pe bi iluu naa se tobi to,ko si banki iyen ile ifowopamo Kankan niluu
naa lati bi odun meloo seyin.
Idi niyii to fi je pe isoro nla ni won
maa n koju bi won ba fee fowopamo, nitori bi won ko ba ti de Ijebu Ode,eyi to
maa n gba won bii ogbon si ogoji iseju ki won to de be, bi won ko ba ti de
be,won ko le rowo fi pamo.
Bakan naa la tun gbo pe opo idaamu lo
maa n de baa won omoleewe Tai Solarin to wa niluu naa,bi won ba fee toju owo,
opo won si ni wahala maa n de ba,nitori bi won ko ba tete rowo toju, tabi gbowo
tawon ebi won ba fi sowo si won.
Won ni gbogbo eleyii ni Otunba Rotimi
Paseda ro,to si pinnu lati fopin si, idi niyii ti won fig be banki naa kale fun
irorun awon araalu.Opo awon araalu ni won si jade lati wa foruko sile lati maa
fowo won pamo si banki naa.
Awon to wa foruko sile |
Ninu oro Arabinrin Olayemi Layeni to je
aare egbe fun ajo awon obinrin ti Paseda Legacy Foundation lo ti so pe ohun ti
banki naa tun wa fun ni lati maa ya awon eeyan lowo lati fi sise, tawon ko si ni
gbe ele lori owo ti won bay a awon eeyan naa. O ni eleyii yoo tun di isoro
ainise ati iponju ku lawujo.
Bee lo tun so pe kii se Omu Ijebu nikan
lawon fee da banki Heritage naa sile si, won ni yoo tun wa lawon ijoba ibile
kaakiri ipinle Ogun ati pe leyin eleyii,ijoba ibile Obafemi Owode lawon tun n
loo.
Awon Obinrin ajo Paseda Legacy |
Nigba ti Baba agbalagba kan,Alagba
Idowu Ojubanire toun naa gbe ilu naa ba oniroyin wa soro, o ni banki naa dun mo
awon ninu, nitori pe nitori pe Ijebu Ode to jinna sawon ni ko je ki opo won ni
ajeseku, o wa dupe lowo Rotimi Paseda fun ero rere to gbe wonu ilu naa.
No comments:
Post a Comment