Lati fopin si orisirisi idaamu to n
koju omo eda, gbajumo olorin emi nni, Efanjeliisi Toyin Alo ti gbe rekoodu
tuntun jade nibi to ti sagbekale awon orin iyin, orin ebe ati adura fun itusile
omo eniyan, to si pe akole e ni Alagbara.
Saaju asiko yii ni gbajumo olorin
emi yii ti koko gbe awon rekoodu kan jade, paapaa akoja ewe e to pe ni Esteban
Praise. Rekoodu ohun lo koko fun un lokiki, to fi deni ti won mo daadaa lawujo
awon olorin. Leyin eyi lo se awon mi-in bii; Oba mi de, eyi to se pelu
Kenny Kore, leyin naa lo tun se Halleluyah. VCD ati Audio CD Alagbara lo wa
nita bayii to n se daadaa laarin awon ololufee orin.
Ninu oro e lo ti so pe, “Rekoodu
tuntun ti mo sese se yii, iyen ALAGBARA, awo orin to yato si ohun ti a ti n se
bo tele ni, gege bi igbagbo temi ninu ise orin ti mo yan laayo yii, orin iyin
ni mo maa n ko lati fi saponle Olorun. Fun idi eyi, orin iyin ponbele ni, ohun
to si da le lori ni oore nla ti Olorun n se ninu aye omo eda ati itesiwaju e
ninu aye kaluku. Pelu bi nnkan se ri lasiko yii, orin iyin, orin ebe ati adura
la nilo lati fi ba Eledaa wa soro ki aye wa le roju daadaa. Okan lara awon
akosemose ninu ka se atopo orin, iyen Ben Jossy lo satokun agbekale VCD yii ati
Audio CD. O da mi loju pe orin emi ti yoo mu ilapa rere ba aye kaluku ni, ti
aye yin ko si ni wa ba kan naa mo.”
O fi kun oro e pe, “Latigba ti a se
rekoodu akoko la ti n te siwaju, ti Olorun alaaye si duro ti wa. Eyi gan an lo
sokunfa rekoodu tuntun ti a pe akole e ni ALAGBARA yii, nitori o ye ka polongo
ise rere ti Oluwa n se ni, oun nikan ni o lagbara nla ti o le fi yo omo eniyan
kuro ninu ajaga ti eda n fojoojumo aye ko ara won si, mo si nigbagbo pe,
ayipada rere ti de si orile-ede wa ati idile kaluku.
No comments:
Post a Comment