Ohun ara meriyiri nile isenbaye Hubert Ogunde nilu ososa - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 21 July 2017

Ohun ara meriyiri nile isenbaye Hubert Ogunde nilu ososa


Ara ohun kan pataki ti won maa n se fawon eeyan to ba ti kopa to joju lawujo ni lati maa se nnkan iranti ti ko ni je kawon ise ti won tise nigba to wa laye parun,nitori opo irandiran to ba n rawon nnkan wonyii ni yoo mo pe enikan wa to ti se ohun ribiribi,ko to faye sile.
 Hurbert Ogunde

Irufe nnkan bee lo wa niluu Ososa nijoba ibile Odogbolunipinle Ogun,nibi ti ile isembaye tawon oloyinbo n pe ni Museum kan to je ti agba oseere onitiata nni Oloye Hubert Ogunde,nibi ti won ko awon nnkan ti Baba naa lo latigba to ti bere ise tiata titi di akoko tiku fi muu loo iyen ni nnkan bi odun metadinlogbon seyin.

Lodun 2015 ni a gbo pe won si ile isembaye naa iyen lakoko ti won se iranti ayeye odun keedogbon ti agba osere tiata faye sile, lojo naa lohun, awon oseere tiata ti won kose labe Baba naa atawon ti won je omo omo fun Baba naa nidi ise naa peluu awon eeyan Pataki lawujoi ni won wa sile naa.

Latigba naa ni awon omoleewe to fi mo awon araalu jakejado orile ede yii ati ni oke okun ti n wa siluu Ososa lati wa wo awon ise ti Baba naa se,eyi to je ki won so ile naa dile irinajo igbafe tawon oloyinbo n pe ni Tourism.

BO SE RI naa sabewo sile isembaye Hubert Ogunde naa lati wo awon nnkan ribiribi ti won ko pamo sinu ile naa ati idi tawon eeyan fi so ibe di meka won lati loo maa wo nnkan to sele.

Iwaju ile isebaye Ologbe Hurbet Ogunde
Okan lara omo omo Baba naa, Adeleke Ogunde lo gba wa lalejo to si mu wa kaakiri ile naa, irinajo naa bere lati ita titi wo gbogbo inu ile naa.Beeyan ba ti koko wonu abawole ogba isembaye naa ni yoo ti koko ri moto nla meji kan. Gege bi a se gbo, awon moto yii ni won so pe Baba Ogunde atawon osere e nigba naa maa n gbe jade ti won ba ti fee loo sere.

Bee naa ni egbe moto ohun ni faanu kan wa to dabi tii baalu to maa n fo loke, won ni kinni ohun ni won maa n lo nigba naa gege bi idan iyen effect ninu awon fiimu ti won se nigba naa.
Bakan naa legbe ile abawole senu ile isembaye naa ni won ni won si Baba Ogunde se, ere ti won fi mo Baba naa naa peluu ilu nla tawon awo maa n lu ni won mo sibe,egbe tohun ni won gbe ere mama to bi Hubert Ogunde naa si.
Bee lo tun se je pe ti won ba fee wole lawon eeyan yoo ri lawon awon iwe Baba naa,pabanbari e ni inu ile naa nibi ti won nnkan lorisirisi ti Baba yii lo lakoko to n se tiata wa.

Moto tegbe osere Hubert Ogunde n lo nigba ti won ba fee rinrin ajo
Lara awon nnkan ti BO SE RI tun ri ninu ile naa lawon aso orisirisii bii aso olopaa, asi Eegun iyalode,aso gbewugbewu,aso eegun Omolokun Agbo,aso awon agbetu atawon aso min in,ti won maa n lo lori ere itage atawon fiimu ti won se nigba ti on wa laye. 


Ogbeni Adeleke Ogunde tun safihan awon foto lorisirisi ti Baba naa ya peluu awon osere tiata lakoko ti won wa n se ipade egbe osere tiata lodo e, awon foto tawon eeyan bii Ologbe Oyin Adejobi, Oloogbe Duro Ladipo, Oloogbe Kola Ogunmola, Oloye Jimoh Aliu,Alagba Mosses Olaiya topo mo si Baba Sala atawon osere min in wa ninu won. 

Bakan naa lawon akosile orin ati fiimu tun wa ninu ile naa,ibi ti ibusun e wa latigba to ti ku ni nnkan bii odun metadinlogbon seyin lo si wa di oni yii, awon nnkan lorisirisi ti won maa n lo fun idan ni awon bii fiimu Aye, Jayesinmi, Ayanmo, Aropin n teniyan atawon min in ni won lawon sakojopo e ninu ile naa. 

Lara awon ere ori itage ti Baba naa se nigba ti won wa laye
Adeleke so pe idi pataki tawon fi ko ile isembaye naa ni lati maa se je ki ise ti Baba won se nigba to wa laye pare. O so pe milionu lona ogbon naira lawon fi pari ile naa. 

O ni gbogbo enu loun fi le so pe ko si owo ijoba ipinle Ogun kankan ninu ile tawon ko naa.Nitori awon molebi lo pawopo sise naa loruko Baba won, bo tile je igba kan ti Gomina Amosun seleri pe awon yoo ran awon lowo sugbon tawon ko ri nnkankan di akoko yii.

O wa lo akoko naa lati fi kesi awon eeyan awujo, bi awon omoleewe, awon ti ooteli, awon banki atawon eeyan yooku lati wa maa sabewo sile Isembaye naa,nitori awon ohun itan ti ko se gbagbe lo wa nibe.
Bee lo tun so pe won tun le kan sawon ni www.Hubert Ogunde.org tabi www.ogundemuseum.org ati you tube pg-ogunde museum

No comments:

Post a Comment

Pages