Idanilekoo naa ti
Onarebu Adekunle Adeyemi sagbateru e ni gbajumo agba agbejoro nni, Oloye Wole
Olanipekun ti da awon eeyan lekoo ni Seneto Bode Mustapha ti soju Oloye
Olusegun Osoba nibe, oun naa lo sit un je alaga nibi eto naa.
Lara awon to tun wa
nibe ni Oludije fun ipo gomina labe egbe oselu PDP, Alaaji Gboyega Nasir Isiaka
topo mo si GNI, Arabinrin Bola Ilori, Onarebu Allen Taylor Agbejoro Ajibola
Kaka to soju igbakeji gomina tele nipinle Ogun, Omooba Segun Adesegun atawon
eeyan jakanjakan lawujo.
Nigba to n soro nibi
idanilekoo naa, Oloye Wole Olanipekun gba awon Yoruba nimoran latii rii pe won
wa gbogbo ki isokan le w anile Yoruba, o so pe gbogbo igbese tawon eeyan n gbe
lati rii pe eya onikaluku loo lotooto, ko le seese laijepe won fi mo sokan.
Bakan naa lo
sapejuwe olojoobi naa, Oloye Segun Osoba gege bi asaaju to fi se awokose rere,
o lawon ipa to ti ko kere rara, o ni bo tile je pe o tipe die to ti fipo naa
sile sibe awon omoleyin e si wa peluu e.
Ninu oro Onarebu
Adekunle Adeyemi to sagbateru eto naa, o so pe o se Pataki lati maa se iru
nnkan bee fun Oloye Olusegun Osoba, eni to sapejuwe gege bi ologbon, to niwa
irele ti kii fomo eyin e sere.O ni opo awon eeyan lo ti tipase akoni naa dide.
O wa gbadura pe ki
Olorun tunbo ro okunrin naa lagbara lati fit un se opo odun laye. Leyin ti won
pari eto naa lawon musulumi seto adura nla fun ti ayeye ojoobi naa.
Ola ojo Abameta
Satide ni ayeye naa yoo tun tesiwaju nigba ti won yoo se isin ope fun okunrin
naa nile e to wa ni Ibara Housing niluu Abeokuta.
No comments:
Post a Comment