MOBIYINA OSHOFFA |
Bi iroyin to
te wa lowo yii ba fi le je ooto, inu ayo nla lawon olori ijo Sele ti won fesun
sisowo ijo basubasu kan yoo wa nitori bi won se ni awon olopaa to n se iwadii
naa lati Abuja se ti dawon lare lori esun naa.
Gege bi iwe
kan to te BO SE RI lowo lati gbo pe won awon olopaa ti won n se iwadii naa ti
so pe awon eeyan naa ko jebi awon esun ti won fi kan won peluu awon eri to wa
lowo won.
Awon ti won
fesun tawon olopaa se iwadii naa kan ni Alagba Emmanuel Mobiyina to je olori
ijo Sele, Ajihinrere agba, Pius Olanrewaju,Ojogbon Bola Akinterinwa,Ajihinrere
Segun Aina ati Ajihinrere Samson Olatunde Banjo.
Ninu iwe to
te wa lowo ni won ti so pe ofiisi igbakeji oga agba fawon olopaa to ri si eka
iwadii lo ti so pe ejo ti okan lara igbimo agba ijo naa John Rotomo Omotoso pe
awon eeyan naa ko lese nile.
Iwe ti abala
e je metalelogun ti won lawon olopaa naa fi sowo lati Abuja ni won peluu eri
tawon eeyan naa ko kale, awon ko ri esun Kankan ka si won lese.
Bo tile je
pe latigba ti iroyin naa ti jade lawon igun keji ti n so pe awon ko tin ii
gbagbo ninu e, nitori pe awon to gbe abajade naa sita ko gbo tenu enikeji,ati
pe igbese ti n loo lowo lati tako iwadii awon olopaa naa.
Sugbon peluu
bi won se ni awon olopaa se we awon eeyan naa mo gege bi a se gbo, igbejo si n
te siwaju ninu osu kesan odun yii, nibi tawon igun mejeeji yoo ti mo ibi ti won
n loo.
No comments:
Post a Comment