Osu to koja yii ni
oga agba patapata fawon fijilante nipinle Ogun, VSO, Ogbeni Soji Gazallo pe
odun kan to ti dori ipo naa, to si ti n se adari fajo naa. Bo tile je pe opo
ipenija lokunrin naa ti koju sugbon ti Olorun Oba muu saseyori. Laipe yii
lokunrin naa gba BO SE RI lalejo ni ofiisi e, nibi to ti ba wa so opo oro nipa
ise naa, ati awon atileyin ti won gba lodo ijoba eyi to je ki aseyori tun po si.Eyi
lawon oro to ba wa so.
Ta
ni Soji Ganzalo
Bi a ba ni ka maa so
itan igbesi aye wa nibi ti a ba a de yi, Mo ro pe ile a kun die, a fi ka ge
peepeepee. Oruko mi ni Soji Ganzallo, mo wa lati idile Adebayo Ishola Ganzallo
ti won je omo bibi ilu Abeokuta lati Ake, nibe ni won bi mi si.
Mo loo si ileewe alakobere niluu Ibadan, mo tun
loo si ileewe girama ni Iseyin District
Grammar School, nigba ti mo kuro nibe, ni mo tesiwaju ninu iwe mi, nigba ti
mo loo sileewe giga poli, iyen Ogun State Polytechnic nigba yen, to ti wa di
Moshood Abiola Polytechnic bayii.
Leyin ti mo setan nibe ni mo loo si yunifasiti
ipinle Ogun, Ogun State University, OSU ko too di pe mo bere sii ni sise ijoba ni
Ogun State Agricultural Development Programme ti a mo si OGADEP ko to di pe mo kuro nibe lati tun loo kekoo loke
okun nipa imo aabo, ti mo wa fi n sise se lonii in.
Igba ti mo de ni mo wa di eni to n darapo mo
ajo Fijilante, iyen Vigilante Service of Ogun State, VSO ti a da a sile lodun
2011. Mo bere lati ibi ka maa sise aabo ati alukoro ajo yi, ko to o di pe mo wa
fi gun oke agba lati di adari ipinle Ogun, iyen State Commander ni ojo kejila osu
karun odun 2016. Bi a ba ni ka wo o daadaa, mo sese pe odun kan ni bayii.
Awon
wo la n pe ni Fijilante
E je ki n so bi
Fijilante se je gan an ni pato. Fijilante ni agbofinro to wa laarin awon eeyan
wa, to n sise laarin awon eeyan wa lati je ki aabo pe ye. Bi nkankan ba sele
lawujo wa, awon to n gbe be, ti won gbo ede, ti won mo oju ile, awon tawon
eeyan wa fokan tan, awon ni won maa koko fi to leti, awon yi la mo si
Fijilante, to je pe won wa laarin awon eeyan wa.
Ifokanbale wa fawon eeyan wa to je pe bi won
ba so fun won nipa nnkan to n sele lawujo, A mo ara wa, ti awon kolorosi eeyan
ba wo agbegbe kan, ti a ba ni ka wo o daadaa, awon to je Fijilante ni won ma a
koko mo pe ajeji leni yi, ki i ba wa gbe teletele, ise Fijilante gangan niyen,
lati ri i pe won n mojuto aabo to wa ni gbogbo agbegbe wa.
Ise aabo to pe ye ni igberiko, ni aarin ilu
wa, awon to n ba wa gbe, ti a jo n sun,
ti a jo n ji, awon ni Fijilante, ti won n mojuto aabo wa, ta a ba ri nkankan to
ku die kaato lori oro aabo, a le sare pe won lati fi to won leti, ti won a si
se nkan to to, ati ohun to ye lesekese, ti kii se pe bo ya a fe e duro dola
tabi ose to n bo.
Idi ti mo fi mu ise
fijilante lokunkundun
E se e, ti e ba wo
igbesi aye mi daadaa, igbesi aye mi bere lori ki n maa sin awon eeyan mi. Nigba
ti mo wa nile eko, mo je oludari ti a mo si aare egbe awon akekoo Public
Administration.
Mo fe ki n maa sin awon eeyan mi lawujo ibi ti
mo ba wa. Ko to o di pe mo loo ko eko nipa eto aabo, mo ti n sise pelu olopaa,
eyi ti a mo si Police Community Relations Committee to je ajosepo awon araalu
atawon olopaa.
Bi a ba wo daadaa,
ni gbogbo igba temi bere pelu won, ajosepo araalu pelu olopaa ko dan monran
rara, won ko ri olopaa gege bi eeyan rere. Awon ise ti mo yan laayo niyen nigba
ti mo wonu egbe PCRC lati ri pe a se atunse pelu awon elegbe mi ti a jo n sise
papo nigba naa.
Latigba naa ni won
ti fi mi si ipo lati maa yanju aawo to wa laarin awon Fijilante to wa nipinle
Ogun, nitori pe se ni won pin si orisii mewaa. A ni lati ko won papo sona kan.
Nigba ti mo ti keko
nipa aabo, mo wa a ri gege bi ojuse mi fun ipinle mi to je ipinle Ogun lati ri
pe aabo to peye fese mule ni gbogbo awon igberiko. bi e ba wo ise Fijilante, e
e ri pe ise aabo awarawa, iyen grassroot security la n se, ti mo fi wa bere si I
se ise aabo, to je pe ibi ise Fijilante ni mo wa a yan laayo lati bere. Ki wa a
se pe Fijilante nikan, ti e ba ti wo o daadaa, e e ri pe ati olopaa, ati soja
ati sifuu difensi patapata ni mo n ba ni ajosepo lori oro aabo. Gbogbo awon eka
to n sise aabo nipinle Ogun ati kaakiri orileede Naijiria ni Soji Ganzallo n ba
se papo lati rii pe ilosiwaju eto aabo to pe ye wa nipinle Ogun.
Ise Fijilante ti wa tipe, ode la n pe won
Bi a ba ni ka wo ise
ti Olorun koko da nigba to da ile aye, ise ode ni. Nigba ti Olorun da awon
eeyan sinu ogba Edeni, Olorun fi won so ara won, ibe ni ise ode ti koko bere.
Gbogbo ode ti a n so
yii, emi gan an, bi mo se n baa yin soro, olori oga ode ni mi, Olopaa, ode ni,
Soja, ode ni, Sifudifensi, ode ni, ise ode ni gbogbo wa jo n se, o kan wa yato
si ara won ni.
A ko le wa fi oju ti
atijo wo o iru ode ti a je, ode aperan wa, ode to n so eeyan lawa je, awa kii
se ode apaayan. Ode ti a n se ni lati sode awon kolorosi lawujo wa, iyen awon
odaran, obaluje tabi awon ti won le ba aabo wa je lawa n se lati mu won.
Lori oro ti e beere,
ise ode lasiko igba yen, tawon baba wa n so odi ilu, igba yen, e e rii pe bi
won ba n so oja to tobi repete, o le je enikan soso lo maa wa nibe, awon eeyan
a wa maa beere pe bawo ni baba agbalagba yi se n so oja to tobi too yi, o ni bi
won se n se e, o ni ogbon ti won n da si.
Ise ode naa ni won n
se. Ise ode yi naa lo dagba soke, lo gberu, ni gbogbo eka to wa n yo jade ninu e
ti bere sii yo jade, eyi ti Fijilante ko gbeyin ninu e. Ise ode ni ode n je.
Ogbon ta n da si
fijilante ti wa, to fi yato sode
Mo ti so saaju pe mo
loo soke okun lori oro aabo, oro aabo ti koja wi pe a n de igbadi, onde, a n se
oogun lati so ilu. O ti koja be. Awon ti won n digun wa ba wa laariin ilu, awon
ti won n ja wa lole, awon naa n soogun. Bi o ba wa a je oogun la wa ni a fe e
gbekele lati maa fi sise ode, se e rii pe a a fe mehe die. O ti yato. Ona
igbalode la fi n sise aabo lasiko yi, kii se pe ka maa di igbadi mora tabi onde
mora kaakiri.
Mo nigbagbo pe ogun
wa
Se
la
maa n tan ara wa je lorileede ti a wa yi ni, awon ti e n so pe won ko nigbagbo
pe oogun wa yi naa n se oogun. Ti a ba wo o daadaa, a ti ri eni to je pe Pasito
ni, to je pe o n kede igbagbo fawon eeyan, sugbon nigba ti isele sele, ti won
tu ara e, won ba oogun lara e.
E so fun mi, se ko
nigbagbo ninu oogun lo n di mo ara kaakiri, a bi bawo lo se de ara e? Bee naa
ni ti elesin keji naa, iyen awon Musulumi ti a mo. Awon te n soro won yii naa
iyen awon olopaa, soja, ti won ba n loo soju oogun, opolopo n de nnkan mora ki
won to lo.
Bi a ba so pe ko
soogun, a n puro tan ara wa je ni. Emi o le ba eeyan so pe ko soogun o, sugbon
ofin ile wa ko fese e mule pe oogun wa. Ti mo ba so pe eni kan lu mi ni ogun,
to mu mi maa wu awon iwa kan, ko si ofin to fese e mule pe nkankan wa ti won le
fi lumi to le mu mi maa wu iru iwa bee.
Ona ti won maa fi to
ni ona igbalode, ki won gbe onitohun loo sileewosan, ki won si wo bawo lo se
je, kini nkan yen se sele sii, ohun ni ona ti a mo laye taa wa niisinyi.
Ohun lo fa to fi je
pe ijoba ko gbagbo pe oogun wa, a o le lo sile ejo lati lo maa rojo pe oogun lo
fi na mi, o ni lati le fese e mule ni ona iwadii tigbalode pe nnkan to fi na mi
yen lo sise yi ti o de le nira die lati se, lo je kawon eeyan maa wo pe ko
soogun. Sugbon bi mo se jokoo ti yin, emi mo pe oogun wa o, ka ma so pe ko
soogun.
Aseyori mi laarin
odun kan gege bi oga agba
E se pupo. Mo dupe
lowo Olorun alaaye to gba wa laye, to si fun wa ni alaafia pipe lati le sin
ipinle ati orileede wa Naijiria. Lenu odun kan ti mo di oga agba ileese
Fijilante nipinle Ogun yi, ee ri wi pe iwuwasi awon Fijilante, mo ti gbiyanju
lati yi pada lopolopo lati ri wi pe gbogbo ise ta ba n se, a gbodo se pelu ofin
nitori pe eto awon eeyan wa labe ofin wa nibe.
A o gbodo te awon
eeyan wa loju mole. E e ri wi pe bi Fijilante se n sise ti yato si tigba kan,
ko si pe bi Fijilante ba mu enikan, o maa so pe won n lu oun tabi won fi iya
aito je oun tabi won lo ti oun mo ibi kan. Gbogbo iwa bee ti kase nile ninu
Fijilante.
Gbara ti mo ti di
oga agba pata ni mo ti jade loo kaakiri gbogbo ibi ti eka wa wa lati ri pe ko
sibi kan ti won n pe ni seli nibi ti won le ti eeyan mo ni gbogbo eka ti a ni
nipinle Ogun.
Bi won ba ti mu
eeyan, a fi ki won loo fa a le olopaa lowo. Lona keji ewe, e e ri pe imura awon Fijilante
lenu igba ti mo debe yi ti yato si bi won se n mura tele. Aso buraun (brown) la
n wo tele, aso to gba idoti ni, sugbon a o tun gbodo ri ara wa gege bi onidoti
eeyan, lati fi wa yii pada, e e ri pe iwoso won ti yato si tele, won ti n mo
yato, bi won se n wo bata naa ti yato. A tun ti wa n gba awon eeyan kun awon ti
a ti ni tele, kii sii se pe a n gba awon eeyan ti ko loye. Eni to iwe eri to
kere ju ni eni to ni iwe mewaa, kii waa se iwe mewaa lasan, o gbodo yanranti.
Kii se pe pe boya mo
kawe mewaa, mo wa feeli, Fijilante lo ku ti mo wa fe e se, ko ri bee.
Idanilekoo loorekoore la n se fawon eeyan wa lati ri pe a ko won lawon nnkan to
ye ki won mo lati sise won bo ti to ati bo ti ye.
Lasiko mi, niwonba
odun kan to koja yi, bi eemefa la ti se idanileko ni ileewe wa. Asiko ti mo di
oga agba yi ni a da ileewe Fijilante sile, ti a pe ni Vijilante Academy to wa nilu Ilaro nibi ti a ti n ko awon eeyan
lekoo.
Ijoba ipinle Ogun lo
si fun wa nibi ti a n lo, ti won si fun wa lawon nnkan to ye ka ni, eyi to n mu
ise rorun fun wa. A tun n ran awon eeyan wa jade sita. A ti se idanileko
alapapo olosekan gbako pelu awon Sifu difensi, a ti se pelu awon olopaa to je pe
awon olopaa ni won wa si ile eko wa lati wa da awon eeyan wa lekoo lori oro
aabo.
Leyin ti mo debe, mo
ti se igbega fawon oga kaakiri ti a fi kun ipo won, opo won la so di apase,
(director) ni gbogbo awon eka ti a ni nipinle Ogun. Awon oga agba lekun
kaakiri, iyen Zonal Commander la tun ti ro lagbara ju ti tele lo lati le sise
bo ti to ati bo ti ye.
Leyin ti mo de be ni
won tun da ijoba ibile idagbasoke, LCDA ti won yo lara ijoba ibile ogun, ti a
ni tele sile, lasiko yi ni mo ti yan awon alakoso sibe kaakiri. Ti e ba tun wo
o daadaa, laarin odun kan yi, a ti sise takuntakun pelu awon olopaa lati sise
papo ko awon kolorosi eeyan lawujo wa, paapaa awon adigunjale ti won ko je ka
gbadun lowo wa ti te, awon to wa ni tesan ti wa nibe, tawon min in si ti foju
bale ejo.
Awon ise ti a ti
seyin ko see fenuso tan, eyi lo je ki ijobba ipinle Ogun funra e kan saara si
wa pe ise la n se.
Emi o ti e ri awon ti
won yapa loo si VGN rara depodepo pe maa mu won gege bi orogun. Bi a ba ni ka
wo o daadaa latigba ti won ti pe ara won ni nnkan ti won n je, e so fun mi,
araalu meloo lo gburo won. ole meloo ni won ti mu, ijoba wo lo mo won, araalu
meloo lo mo won, awon wo lo ti gba won lati gbe ise fun won ti okan won si bale
lori ise ti won gbe fun won? Emi o ro pe o ye ka ti e la ara wa loogun lori
eleyi rara.
Ise ti a mu
lokunkundun lati se ni aabo awon eeyan wa, mi o ri won bi orogun rara. Ise ti a
gbe siwaju, tijoba gbe le wa lowo, tawon eeyan wa gbe le wa lowo lawa n se, ki
Olorun ko ran wa lowo.
A n se idanilekoo
fawon fijilante to ba n lo ibon.
O wa daadaa, tori e
ni mo se soro nipa ileeko ti a sese da sile, ti a si n pe awon olopaa lati wa
fun awa Fijilante ni idanilekoo. Ise yi, ise to lagbara ni. Kii se gbogbo omo
egbe Fijilante lo n gbe ibon, sugbon iwonba awon to n gbebon gbodo gba
idanilekoo to to ati eyi to ye nitori ohun ija ti won gbe dani yen, lati fi
daabo bo awon eeyan wa ni, ko gbodo tun je ohun to gbodo se awon eeyan wa lose.
Idi ni yen ti idanilekoo fi n waye ni gbogbo igba.
Ipenija ti a koko
koju
Looto ni, e se.
Ipenija ti a ni ni ti aini owo to to, eyi to n ba gbogbo awon ijoba wa finra.
Awon nkan to ye ka ri gba lati owo ijoba lati fi se awon nnkan ti a fee se, aini
owo ni ko je ki a le se awon nnkan min in.
Bi e ba wo gbogbo
awon moto wa ti a n lo, ti a n pe ni patrol vehicle yi lati gba lati odun 2011,
to je pe won ti gbo, won ti denu kole. Ara ipenija ti a ni niyen, sugbon a
tiraka lati tun won se, won ti pada senu ise, eyi naa tun je lara awon aseyori
ti mi o ranti menuba.
Ipenija nla to daju
ni ti ainito owo. Awon moto to ye ka maa fi sise ni ko to, bee naa ni ti awon
irinse to ye ka lo lati fi koju awon kolorosi eeyan ni ko si. Bakan naa ti e ba
wo, ijoba ko lo n san owo gbogbo awon osise Fijilante ti a ni nipinle Ogun,
iwonba la n gba lowo won, funra wa la n tiraka lati san owo fawon toku, awon to
n gbese fun wa, owo ta n ri nibe la fi n sanwo fun won, sugbon Olorun n ti wa
leyin lati koju ipenija yii.
Ijiya wa fun
fijilante to ba si ise se
Gbogbo idanilekoo ti
a ni a n se fawon eeyan wa, awon kan wa ti a pe ni orientation programme lati
maa fi ran won leti awon ilana ati ofin (code of conduct) ajo Fijilante, eyi to
so nipa bi won se gbodo huwa, awon nkan to ye ki won se atawon nkan ti won o
gbodo se.
A rii pe akoko se awon nkan yen fun won lati ran won
leti ise won lawujo. Leyin ti a ti se awon nkan won yi tan, a a waa ri pe ko
seni to maa wa so pe oun ko mo awon nnkan to ye.
A tun ti wa yan awon
kan to je pe awon ni won wa nidi ibi ti won ti n ye ejo awon eeyan wo, ti won
si n so awon ijiya to to fun iru awon eeyan bee. Eni to ye ka da duro fungba
die, a a lo, eni to ye ka le danu patapata, a a lo, eni to ye ka ro loye, a a
se. ti e ba ri lenu ojo meta yi, e e ri pe e o le gburo Fijilante pe ko wu awon
iwa ti ko bojumu lawujo, gege bo se wopo tele.
Ko si isinmi rara
nidi ise yii, sugbon sa.
Ko ma si isinmi rara
fun mi. ti m ba ti debi ise laaro, o tun di ale patapata ki n to lo sile, ale
ti mo ba tun loo sile naa, ero ibanisoro mi o gbodo ku, o gbodo wa legbe mi
niseju-iseju ni, nitori pe bi won ba pe mi pe won ni ipenija nibikibi, mo gbodo
pe awon oga to wa lagbegbe naa lati lo o ba won. Bi mo sun naa, oorun
aisundokan ko si.
Ojo Aiku Sannde ni mo maa n fi sinmi, ti m ba
ti se tan nile ijosin, maa wa sibi ise, ise ojo yen kii dabi taarin ose. Ti mo
ba ti wa sibi ise yi, ori aga to wa ni ofiisi mi ni mo maa rora fegbe lele si
lati sinmi die.
Leyin wakati meta
maa sese loo sile lati loo ba awon ebi mi sere, ti maa si gbe won jade loo sibi
to ba wu mi. Asiko yen ni mo maa n ri aaye lati ba won sere, ti a si soro
molebi, oro baba somo, oko si aya.
Awa
naa ti n gbaradi fun eto aabo fodun2019
Imurasile Fijilante
atawon osise alaabo ni lati rii pe a so akiti mo apa lati ko gbogbo awon
kolorosi eeyan to wa ni awujo wa to le fee ba oselu awaarawa yi je, a pale won
mo.
Awon kan wa to je pe
asiko oselu yii ni won maa loo ko ibon wole, ti won a loo yo ada, ti won a loo
ko awon ohun ija oloro lati lo maa fi sose fun awon oloselu alatako won tabi
awon ti won ba n ba ara won dupo.
A ti mura sile lati
se ohun to to ati ohun to ye. Nnkan to sele ni pe ko si eyi to kan wa pelu oro
oselu. Osise alaabo kankan ko gbodo fara mo egbe oselu kankan, a gbodo rii daju
pe aabo to peye wa fawon araalu lasiko idibo. Okan awon araalu gbodo bale pe
asiko to m bo yi, ko nii si wahala fun won.
No comments:
Post a Comment