Adajo ile
giga tijoba apapo keje to wa niluu Ikoyi, nipinle Eko, Onidajo Chuka Austine
Obiozor ti pase pe ki igbejo bere lori esun sisowo ijo basubasu ti won fi kan
awon olori ijo Sele kan,eyi ti yoo bere lojo ketadinlogbon ati kejidinlogbon
ninu osu kesan odun yii.
Nibi igbejo
naa to waye lojo Aje Monde tii se ojo karun un osu kefa nibi tawon agbejoro
olupejo ati olujejoo ti jo gbena woju ara won lori awon ebe ti olujejoo be ile
ejo lori awon esun naa lati se itewogba.
Awon
agbejoro fun olujejoo lojo naa ni Agbejoro Wole Okelile, E O, Omodiade, Rasheed
Muyideen nigba ti O Fabunmi,M Odumuyiwa
ati Akiniyi Obisesan je agbejoro fawon olujejo.
Alagba John
Rotomo Omotoso to je okan lara awon igbimo agbaagba ijo sele lo pe olori ijo
sele atawon merin min in lejo lori bo se ni won sowo ijo naa basubasu ati bo se
ni won tun loo n loo banki min in to yato si eyi ti ijo n lo.
Awon to pe
lejo naa ni Mobiyina Osoffa to je olori Ijo naa,Ogbeni Segun Aina,,Ogbeni
Samson Olatunde Banjo,Ojogbon Bola Akintehinwa ati Ogbeni Pius
Olanrewaju.Gbogbo awon olujejoo ni won yoju nibi igbejo to waye naa ayafi olori
ijo naa, ti agbejoro e soju fun un.
Bo tile je
pe nibi igbeji akoko to koko waye ni Adajo naa ti fun won lore ofe boya pi ki
won loo yanju e labele ki won si wa fabo je won, nibe naa si ni Adajo naa ti
bere lojo naa sugbon ti won ni gbogbo ona lati pe ipade lati yanju e ni ko yori
sir ere, idi niyii to fi ni ki won kuku bere ni pereu.
Sugbon sa,
won satunse lori ebe ti olujejoo be ile ejo lori esun to pe naa nigba tawon
agbejoro mejeeji jo sise owo ti won gba fun un, lori pe ki won si fofin de awon
banki ti won ti n gbowo jade, kawon olujejoo maa ni anfaani lati gbowo,adajo lo
koko so pe yoo soro se lati gba ebe naa wole,nitori akoba to maa wa nibe, lara
e nip e awon to n sise ti won n gbowo osu ninu ijo naa ko raye gbowo mo, ati pe
nibo ni won ti fee maa rowo ti won yoo maa fi gbo bukata lori ijo naa.
Idi niyii ti
Adajo atawon agbejoro naa se gba pe ki won fun olujejoo laye lawon banki tijo
naa n lo, lati mo bi won se n nawo ijo naa ati pe lati akoko yii loo titi ti
idajo yoo fi waye,ile ejo gbodo maa mo bi won se n gbowo jade ni banki,bee ni o
tun pase pe ki awon olujejoo naa maa se si banki min in lakoko yii yato si eyi
ti won n lo.
Lori ebe pe
ki ile ejo si pase fun olori ijo naa lati da ami ororo ti won fi maa n yan awon
eeyan duro nitori oro po lori e, se ni Adajo naa da ebe nu pe ko lese nile,oun
ko le ni kenikan maa ta ami ororo.
Ebe meji ti
olupejo bebe fun ninu meje ni won yo danu nigba ti igbejo yoo bere ni pereu
lori esun marun un yooku.Ojo marun ni won ti la kale fun igbejo naa, ojo naa ni
ojo ketadilogbo, ojo kejidinlogbon osu kesan,nigba ti yoo tun te siwaju ojo
kerin, ojo karun un ati ojo kewaa osu kewaa odun yii.
No comments:
Post a Comment