Bee lo tun fun lebun owo
Ere ni won koko pe lojoobo Tosde ose to koja nigba tawon
omoleewe girama Muslim Grammar School to
wa niluu Sagamu gbo pe gbajumo osere tiata nni to tun je oludasile Mista Latin
foundation iyen Mista Latin n bo nileewe naa lati wa ri akekoo binrin to ri poosi he ni nnkan bi
ose meta seyin to si muu loo si banki ti eni to ni poosi naa n lo,eni ti oruko
n je Labake, awada ni won pe.
Mista Latin ati Labake |
Sugbon lojiji ti won gbo pe gbajumo naa ti wonu ogba ileewe
naa pelu iko e, ni se ni ileewe naa daru fun ariwo, opo awon omoleewe lo sa
jade latinu ileewe naa lati wa wo oseere
naa, opo won lo je pe won kan n gbo oruko e tele ni amo ti won r nigba akoko.
Won ko si foro naa fale rara ti won
fi pe omobinrin naa jade to fun un ni ebun owo egberun lona ogun naira bee naa
lo tun fun ni awoodu,to sit un fun ileewe tomo naa loo ni awoodu peluu..
Ninu oro Mista Latin lojo naa, o ni
nnkan tomo naa se je ohun iwuri, nigba tawon gbo pe peluu ipo tiya omo naa wa
ati ise to n se, gege bi eni to n gba ile titi kaakiri, ko je ki
ojukokoro woo loju, to fi mu poosi naa peluu egberun mejidinlogun naira to wa
nibe, to si muu loo si banki.
O ni dajudaju eko tawon obi e ko lo
gbe jade, o war o awon omoleewe yooku naa lati fi tie se awokose,bakan naa ni
won tun fun ileewe naa .lawoodu gege bi ileewe tomo naa n loo.
Lara awon to tele Mista Latin loo
sibe lawon omo ajo e atawon omo egbe TAMPAN ti won wa ni Sagamu.
No comments:
Post a Comment