Itu tawon eeyan n pe mi ni bo se je - Baroka. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 3 June 2017

Itu tawon eeyan n pe mi ni bo se je - Baroka.

Beeyan ba pade osere tiata ti won n  pe ni Rasak  Oyadiran topo mo si Itu Baroka yoo roo pe ko le jekoo toro tan ni,nitori boju  e se tutu, sugbon to ba debi ise tiata koo si ara ti ko le da.Okunrin naa ba oniroyin wa Johnson  Akinpelu soro lori bo se bere. Bo se soo ree

Bi mo se bere
Baroka
Oruko temi ni Abdul Rasak Adesina Oyadiran, topo mo si Itu  Baroka. Omo agboole Arabanbi ni Ikereku Idan niluu Abeokuta ni mi.Abeokuta naa si ni won bi mi si.Mo loo sileewe alakobere Holy Trinity bee ni mo tun loo sileewe girama Olumo Secondary Commercial School,ko to di pe mo tun loo kawe gboye imo ijlnle.

Ileewe giga yunifasiti Olabisi Onabanjo ti won n pe ni yunifasiti tipinle ogun tele ni mo ti koko gba imo ijinle akoko ninu ede Oyinbo, Leyin naa ni mo tun loo si yunifasiti tiluu Ibadan nibi ti mo ti gboye masta ninu ise ere ori itage.Gbogbo asiko ti mo fi wa nileewe yii, ni mo fi je osise ijoba nileese to n ri si ere idaraya.Olorun si fun mi ni oore ofe lati di adari leka isakoso ko to di pe mo feyinti lodun 2010.
Bi mo se bere ise tiata
Ise tiata maa ti wa ninu eje tipe, o dabi eni pe bi eeyan sise ijoba, to tun sise tiata, ipe ni mo kaa si,bi oniroyin naa ni,to ba nile nidi ise tiata,ko si nnkan to le se, ipe ti ko see ko nise naa.

Mo ti bere ise tiata tipe tipe,itage,ka ko ara wa jo,lati ere oloyinbo dori Yoruba, ko to di pe mo wo yunifasiti.ko si bi a se le ko ede Oyinbo ti a loo ko,ti a ko ni de ipele ori itage,nitori o da duro labe e ni, iyen tun wa je ki imo tun ga si.ibe  ni mo ti koko gba oruko Baroka tawon eeyan fi n pe mi ninu ere The Lion and the Jewel ti Ojogbon Wole Soyinka ko.

Emi o kose tiata labe eeyan kankan
Mi o ko tiata labe eeyan kan rara sugbon mo nigbagbo pe  opolopo oga ni mo ni nidii ise naa, se e ri imo, beeyan ba se wa imo sii ni yoo maa ri, gbogbo awon baba baba nidi ise yii,oga wa naa ni won je nitori a ri eko ko lara won.Mi o le gbagbe Baba wa Ogunde laye fun ere kan ti won se to muu mi lokan Seranko Seeniyan ni akole e.

Iru awon ere yii je nnkan to je ki tiata wu mi se, ka maa ti wa so kootu Asipa ti Oyin Adejobi,igba naa niwe Atoka to je pe mi o kii fi sere lakoko naa.gbogbo igba yii eko ni mo si n ko.

Gbogbo igba temi naa bere si nii n ko eeyan ko,da tiata sile,ti mo n sere lori redio, mo tie sere fun redio OGBC gan an nigba naa,mo dupe lowo Olorun.
Igba ti mo degbe tiata temi sile.

Mo le so pe mo da egbe osere tiata temi sile ni kete ti mo jade yunifasiti iyen lodun 1989, Egbe naa ti wa tele, ta ti maa n sere olokanojookan iyen ITU Baroka Production,

Fiimu ti mo ti se jade
Fiimu akoko mi ni Oluwa so pe,leyin naa mo se Kii gbe bee ni mo tun se Ikore,sugbon okan wa taa ti se sugbon ti a ko ti gbeje jade, oun la pe ni Arojinle.Ise to ni igba ati akoko ni to si nii se peluu awon oloselu, o si nigba ta le gbe jade,idi ti a ko ti fi gbe jade niyen..

Oyadiran Baroka
Idi ti won fi maa n pe mi ni Itu Baroka
Opo awon eeyan lo maa fee n fun Itu ti mo n je ni itumo sugbon mo fee fi akoko yii so pe leyin Baroka ti mo ti n je ti won fi n pe mi ni Itu naa sese jade
1985 ni won ti n pe mi ni Baroka o ti le logbon odun bayii sugbon nigba ta fee da egbe sile la fi itu kun kun. Bo tile je pe opo itumo lawon eeyan n fun Itu naa sugbon ni ede Yoruba ti won ba so pe Itu ni, nnkan a woo la enu sile ni won n pe bee. A kan fi gbe oruko egbe osere wa sile ni pe awon osere alawo-yanu- sile la wa.

Awon min a maa pe mi ni Itu Baba Ita mo si maa n da won lohun, koda nigba ti ore mi Gbenga Adeboye wa laye to bere si seto Itu, mo pe mo ni Gbenga ona ti tun gba gbe itu tie gba lagbara, oun naa da mi lohun pe Baroka, e Kuku bi Olorun se seda e, ki Olorun forunke.

Iyato to wa ninu Itu mejeeji ni pe ti Gbenga Adeboye, Itu e ni ti Baba adugbo omoota, ko jo temi o,Olorun maa fiyen si wa lokan.

Ere to koko gbe mi jade bi osere tiata
Ha! Oluwa ooo,awon ohun nla le n toka si, se e ri awon ere wa yii, huuumm,mo ranti ere ti mo ba Olaiya Kopa ninu e ti akole e n je Ore, Adajo ni mo se ninu e, Bakan naa fiimu Egbon wa kan, Wemimo,Aye jobele ni akole e, oun ni sinima akoko ti mo le so pe won gbe mi sinu pataki nla iyen bill board ti mo si fi n dupe lowo Egbon naa, fun oore nla ti won se fun mi, kii se pe a gbeeyan sinu paali la n so o, nitori kii se gbogbo osere lo niruu anfaani bee..Awon ere to gbe mi jade po o, mo ba Dele Odule naa sere sugbon mi o le ranti mo.

Ipenija mi nidii ise tiata
Awon ipenija naa po o, mi o le so tan,ara e ni pe ki a be Olorun ki ara maa gbenu wa gbe,ki a ba le se awon nnkan to wu wa, ki a si tun mimo lati le gbe kale. Ipenija to poju ko koja  owo lati fi sise,Olorun nikan lo le ran ise wa yii lowo, yato si pe oto lowo ta maa fi sise, oto ni won yoo ra, ti ko nii ba iye owo ta naa lee lori,ti ere ko yo nibe. 

Owo ta n loo, ko towo ta le lo fun ohun elo fiimu lasan, oun la wa maa ja gba laarin wa,iyen ko le muu nnkan gidi jade.A ni lati be Olorun ko ko si ijoba ninu, a ti so l orisiirisii ona tijoba le gba ba wa da si ise wa.

Nijoba ba n ronu ona lat. i seranlowo fawon odo ise tiata naa wa lara e,emi o rise feeyan n se ti ko raye bi ko se ise wa yii, nijoba ba le ba wa ro awon odo wa lagbara fun iranlowo owo, yoo din ise asewo, ole jija ku lawujo wa. Onikaluku a le maa lo talenti e fun ise wa yii. Bee ni ko ni si pe a maa bere si ni sagbe tabi toro owo kaakiri ka to se fiimu jade. Ijoba naa maa ri tie nibe, bi ilosiwaju ba ba ise kan,aseyori naa ni yoo je fun won.

Itiju ti mo ba pade nidi ise naa
Boya ki n so pe nitori eko ti mo ti ko nipa ere tiata pe ti a ba Kopa awa gangan ko nipa ti a n ko iyen kii je oju ti mi sugbon mo ranti ere kan ti a se Epon agbo lakole e, ore wa ni Abeokuta lo ni ere naa. Ipa oluko to fee fipa  ba omoleewe e sun ni mo ko nibe, ti won de pakute sile fun mi ninu ere naa.

Emi o wa ka ere naa kun, mo ti gbagbe, a fi bi mo se n loo ladugbo Ikeja lAbeokuta, mo pade awon omoleewe meji kan ti won bere si nii sa fun mi, ti won so pe oun niyen, o fee ba omoleewe sun, won ya se fun un, won se fun daadaa. Se loju gba mi ti, nitori loju awon omo yen bi eni pe o sele looto ni, mi o le gbagbe,bigba ki ofe gbe mi kuro niwaju won lo ri.,Sugbon lara ise ta gba ni,  a gbodo fi mora ni..

Ise tiata ko yo lokan mi ri.
Se e ri akoko ta wa yii, awon nnkan to le yose ltiata lemi eeyan ti poju, mo so kin ni kan fun yin pe ipe nise naa,bi a ba yo tipe kuro nibe, opo awon eeyan ni yoo ti sa,tawon to n se yoo ti dinku,Ki ni idi, ise taa rii pe Olorun sunkun, to n loo siwaju. Sugbon awon idiwo yen ti poju.

Fun apeere, e loo sise, iyawo atawon omo yoo maa reti pe  e e ma mu owo bo, ke e wa pari ise tan, ki won wa maa so fun yin pe,e o ni binu o, owo moto nikan la maa ri fun yin.a ko to owo yin san o, eni te o towo e san,te n pe ko wa ba yin sise.Won a tun wa ku owo naa moyin lowo, E tun maa ba elomin in kaanu ti won ba fun ni owo, idi ti mo fi so pe nnkan to to mu ise naa yo lemi eeyan po. Sugbon ise naa ko yo lemi mi ri,nitori ipe ti a pe mi si nii.

Mo faramo ko ni tiata maa sise min in
Peluu bi nnkan se n loo Yi, emi faramo ki onitiata wa ise min in kun ise re titi ti tiata yoo fi gun rege nitori oju tawon eeyan fi maa n wo wa nigboro yato,won maa roo pe bi a se maa n se ninu awon fiimu yen naa lo ta sansan fun wa ti ko si ri bee. Bee ba ri bawon omoota se n se wa nigboro ti won ba fee lawon ja gba,a ni se ni won a tun maa so pe owo awon ko lee fun awon, se won mo bi apo onikaluku se ri nii, o ti sele semi naa daadaa,won so wa d onifuji.

Ko si ojo tinu mi kii dun.
Bi mo se wa yii, ko si Ojo kan laye yii tinu mi kii dun yala nidi ise tiata tabi igba ti mo m sise ijoba,Mo dupe pe Olorun ko pa mi lekun ri,mo so maa n fope fun inn.Nitori oore ofe ti mo ri gba naa ni,bee gbogbo igba ti won ba ti fun lami eye idanilola inu mi maa n dun gan ni,nitori awon eeyan n mo riri ise ti mo n se nii.

Ibi tise tiata ti gbe mi de
Ko tunbo gbe wa debi ire,nnkan ti mo mo gege bawon eeyan se maa n pe wa ni adara ma sun le,ise yii ti je ki n mo opolopo ilu kaakiri bee lo tun je ki n mo awon eeyan, adura mi ni pe kise wa gbewa debi ire.


Ko sojo tinu mi baje ri
Ko si ojo tinu mi ba je,gege bi mo se n so, a n rin ni bebe iku Sugbon Olorun ko je ka ko sii,yato sawon Ojo ka loo ibise ko maa sowo,mo dupe ko sojo to ba mi ninu je.

No comments:

Post a Comment

Pages