Idunnu lo
subu layo fun idile kan toruko won n je Ayodele Ibikunle ti won
ro pe ko si iranlowo mo fomo won ti sese bi nitori aisan kan to koluu sugbon ti
ajo Paseda Legacy iyen PLF ran lowo, ti won si gbemi omo naa la.
Osibitu
kan ti won ti n toju opolo ti won n pe ni Otunba Subomi National Pedeatric to
wa niluu Ijebu-Ode ni won so pe awon obi
omo naa gbe omo naa loo nibi ti won ti fee sise abe fun un sugbon ti owo ti won
fee fi se naa lagbara fun won.
Sugbon
lojo kokanlelogbon osu karun ti a sese lo tan yii niyanu sele nigba ti Olorun
lo ajo PLF eyi ti Otunba Rotimi Paseda sagbateru e dide iranlowo lati maa je ki
aisan naa pa omo ojo
mejo naa toruko e n je iyanuoluwa ti won si san gbogbo owo
ti won yoo fi sise abe fomo naa.
Gege bi Baba omo naa,
Ogbeni Ayodele Ibikunle to n gbe ni
ojule kejilelogbon, Adefisan niluu Ijebu Ode se wi,o ni awon tie ti so ireti nu
patapata lori omo naa,tawon si ti gba kadara pe nnkan to ba fee sele, ko sele,nitori
gbogbo agbara lawon ti sa fun iranlowo sugbon to je pabo ni gbogbo re n bo si.
O ni iyalenu lo je
fawon nigba ti awon dokita ni kawon wa kowo bowe ise abe pe awon ajo kan ti wa
sanwo e.O ni oun ko mo nnkan toun le so,nitori bi idan loro naa je foun,nitori
awon ti Olorun lo fawon yii,
Okunrin naa ni:” Bi mo
se sare de osibitu ni mo ri iwe sowedowo to je ti ajo Paseda Legacy ti won ko
oruko omo mi si, loooto mi o mo alaanu ara Samaria naa sugbon mo dupe lowo
Olorun, mo sit un gbadura fun won Olorun yoo tubo maa bunkun won,gbese ko nii
je tiwon.
Paseda |
Nigba to n soro nipa
isele naa, Ogbeni Micheal Azeez Ogunsiji to je alakoso fun eto iroyin fun ajo
PLF naa so pe igbese tawon gbe naa je lara nnkan ti idasile ajo naa fun.. O ni
Pataki ise ajo naa ni lati maa ran awon eeyan lowo.
O wa mu da gbogbo omo
Nigeria loju paapaa awon omo ipinle Ogun loju
pe awon setan lati maa tesiwaju nipa reran awon eeyan lowo nipa ilera
ati eto eko fawon omoleewe.
A o ranti pe lati
nnkan bi osu meta seyin ni ajo naa ti bere sin ii iwosan ofe ati si san owo
ileewew lawon ekun meteeta to wa nipinle Ogun.
No comments:
Post a Comment