Odu ni Seneto Adegbenga Kaka kii
saimo foloko lagbo oselu, o ti je komisanna rii, bee naa lo tun ti figba kan je
igbakeji gomina nipinle Ogun, ki ori to tun gbe dori ipo asofin nibi to ti n
loo soju ekun Ijebu nile igbimo asofin niluu Abuja.
Laipe yii lokunrin naa sayeye ojoobi
odun karundinlaadorun lorile alaye niluu abinibi e ni Ijebu Igbo nibi to ti lo
akoko naa lati fi dupe lowo Oloru, fun idasi e. Seneto ba oniroyin wa Johnson
Akinpelu soro lori awon iriri e nile aye atawon ipenija ninu aye yii.Awon oro
to so niyii.
Odun meedogun ni mo fi saisan ni
kekere
Adegbenga Kaka |
Bi mo ba ni
ki n maa so nipa awon nnkan toju mi ti ri nile aye yii, ile maa kun o,A fi ka
maa dupe lowo Olorun, Oba asekan maa ku,Oba ti n je emi ni, emi ni, ma se beru.Oba
to je wi pe nigba ti gbogbo nnkan ba pin,o maa fi aye sile pe ka ma se so ireti
nu.Mo dupe fun emi to wa. Opo isoro ni mo ti la koja, ti Olorun ko je ki iji
aye ko gbe mi loo, lati akoko ti a bi mi, titi debi pe a n loo sileewe,a bere
ise a tun ba opo iriri pade sugbon ti Olorun kapa gbogbo won.
Se latori
mama to bi mi ni ki n ti bere ni to je pe o bimo kini in ni, keji ati keta,
gbogbo won si n pada, ko to di pe won bi mi, ti mo tun dele aye tan, fun nnkan
bi odun meedogun ni mi o tie mo nnkan ti won se nile aye. Aisan orisirisii lo
se mi sugbon ti Olorun ko je ki n ba
loo. A tie fee so ireti nu nigba naa lohun, bi kii ba se igbagbo ti won ti fi si mi lokan,oun lo je ki n bori aisan naa.
Opo ogun ni won gbe ti mi nibi ise
Nipa ibi ise naa, a ko gbodo maa fenu ba a, nitori isoro to
ba de, Olorun fi ko eeyan logbon ni.Peluu igbagbo ninu Olorun,ati imo ta ti ni,
o mu wa bori, awon idojuko yen ti poju.Lara e ni ibi teeyan ti n sise,ti won
fun un ni igbega , sugbon ti won ko se afikun owo osu mi.To je pe awon to n pe
mi ni oga, owo osu won ju temi loo.iyen ko je ki n tori e binu tabi tori e fise
sile. Lenu ise kan naa ti mo kuro nigba ti mo di komisanna, ti mo fee pada senu
ise ti mo fi sile gege bi adehun wa,awon ta ba leyin odun meta so pe ko tun si
ona ta fi le pada mo. Igba to si di pe eni ti ko ba ni Baba ati Iya kii degbo
eyin, ti mi o reni to le ja fun mi, mo juwe sile, laiba enikeni soro, bi mo se
juwe sile tan ni Olorun tun ke mi.
Nidi oselu tun n ko?
Gbogbo iru iyen tun loo, ninu oselu naa, ka ni a fee du oye oselu, awon
kan a sadede yo,won a ni ko sona, ti won yoo maa tawo sona,Olorun oba, a sekan
maa ku, a ni nibi towo yin ba gun de lo maa mo.
Laarin ose merin mo ti pade adanwo to
tele ara won
E je ki n
tun so igba kan wa to je pe laarin ose merin,to je pe adanwo to ye ko ba emi
loo sele, to si waye lose merin to tele ara won,Eyi to koko sele lori emi fun
ara mi, iyen waye lodun 1987.Nibi ti taya moto ti fo, ti a fee maa tun se,se
lawon adigunjale yo si mi, ti won gbe ibon si mi leti lona Ibafo.Olorun ba mi
se, ko fi siwon lokan lati yin ibon, leyin ti won gba gbogbo nnkan ti won fee
gba, won ba ti won loo. Ose to tele ni oyun inu iyawo mi, nigba ti esu gbe bo
se n se de, mo dupe pe Olorun ko yo, nitori mi o mo pe ko ni baa rin.Ose to tun
tele lomo kan jana mo moto mi lenu. Adupe pe pelu gbogbo e, Oluwa mu mi bori.
Mi o ni lokan pe mo maa depo ti mo wa
yii
Nigba ti mo
fi siasan odun meedogun, mi o tie roo pe mo le gbele aye mo, depodepo pe mo maa
de awon ipo ti mo de yii. Lati kekere mi, ko sigba ti mo jiroro tabi pinnu pe
ise kan ni mo maa se ti mo ba dagba,nigba ti mo ti roo pe ko si ireti, ni mo ti
fara mi sile fun Olorun pe ara to ba wuu ni ko fi mi da.Mi o kii daba pe dandan
mo gbodo di bayii, a dii ogun, di ogbon, ko si ninu temi, bo se wu Olorun lo n
sola e.
Ko si abamo ninu aye mi.
Senato Kaka |
Ko sigba kankan
ti mo kabamo rii ninu aye mi peluu gbogbo nnkan ti mo n se ati oselu ti mo wa
ninu e,eni to ba ti fi gbogbo e fun Olorun,ko si nnksan to n je abamo, Bi a ba
si ti n ranti oro ti Olorun Oba so pe oun maa danyin wo, peluu ohun ini yin. atomo,
dukia, aya ati oko yin.iyen tumo si pe ko si eda to wa saye to koja adanwo.O
tun ni bi oun ba dan yin wo, e gba bee, nitori leyin isoro, irorun lo maa tele.
Ninu Kuran ni mo ti faa jade, Beeyan ba ti ni igbagbo,Olorun so pe oun yoo mu
iro idunnu wa, Adanwo min in to ba sele, se lo fi n fi wa pamo fun omin in to
le buru ju eyii loo.Adanwo teeyan ba bori la n pe ni iriri aye.
Oselu Nigeria buru pupo.
Oselu ta n
se ni Nigeria, o yato sawon oselu ti won n se lawon orile ede min in,oselu
imotara eni lo po, a kii duro ti Olorun, bee la ki n foro ilu si ookan aya wa,ohun
je ka ni idaamu pupo, bee lo n je ka tojubo awon nnkan ti ko ye ka tojubo.Bi
eda ba ti gba nnkan tawon Alfa maa n pe ni Amona,bi a ti gba pe gbogbo ipo ti
eda ba de afunniso ni won,to fi tokantara sise naa, ile aye a toro fonikaluku. Imotara
eni nikan, oju kokoro, wobiliki, wobia ni opo gbe wonu oselu.Ohun lo si n fa
idaamu ati ojojo ti oro aje wa n se.A si ti n so pe gbogbo awon to n bo leyin,
e je ka di opo Olorun Oba mu.,ka duro si ori otito ati ododo, kii ba je pe
ododo naa tako baba ati iya to bi wa,ka duro sibe.
No comments:
Post a Comment