Adeyinka se kinni fun asewo tan, Lawon yen ba gun pa - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 31 May 2017

Adeyinka se kinni fun asewo tan, Lawon yen ba gun pa

Opo awon to gbo nipa isele to waye lojo Isegun Tusde ana lo si n je kayefi fun won nigba ti won gbo pe awon asewo meji kan gun okunrin kan tiyen si gbabe ku patapata.

Awon asewo naa
Ohun tawon ti ko koko mo boro se je roo ni pe boya awon mejeeji n ja lori okunrin yii lati bawon lasepo, sugbon oro ko ri bee, Okunrin toruko e n je lo fowo ara e fa ifakufa, to si dero orun airorele.

Gege bii BO SE RI, se gbo, won ni Adeyinka Olayinka je okan lara awon alamojuto ise kan to n loo lowo niluu Ifo, nigba tile ojo naa su, okunrin naa ko si fee loo sile loo sun nitori ko le tete mojuto ise ojo keji.

Idi niyii ti won lo fi pinnu lati gba okan lara ooteli to wa lagbegbe naa ti won n pe ni KS to wa ni Ifo lati sun ibe mojumo, ko si tesiwaju nibi to ba ise de.

Sugbon bo se de ohun, ni ara e ti kun, ti ko si fee ko kun lasan, idi niyii to fi pe okan lara awon asewo naa Kudirat Raji lati je kawon jo kona sabe mojumo.Iyen naa si gba peluu adehun iye to maa gba.

BO SE RI tun gbo pe ere buruku lawon mejeeji se mojumo nitori bi Adeyinka se n na si bee loun naa gba pada, won se debi pe ko si sitai ti won ko fit e ara won lorun,ko si si nnkan min in to mu Kudi gba fun, bi ko se pe owo adehun to wa laarin won.

Oku Adeyinka
A fi bile se mo to ye ki Adeyinka mu ileri e se ni wahala be sile nitori bi ko se fee mu  adehun iye owo ti won jo so se, eyi lo so faa ti Kudirat fi pe oro e, Esther  Basiru lati wa wo egbin to kan ohun.

Oto leni ti won gba leti, oto leni tara ta bee loro Esther je, nitori pe bo se gbo nnkan to sele ni emi asewo gbe wo, to ti ko agidi bori bii maalu sunsun, ko gba niseju aaya, ti won lo fi fo igo mole, to koko fi gun ore Yinka ti won jo sun ooteli mojumo yannayanna, ti won sis are gbe loo si osibitu.

Leyin eyi lo sese wa fabo je fun Adeyinka funra e, to si gun un pa. Manija ooteli naa la gbo pe o loo pe awon olopaa tesan Ifo, tosi loo fejo sun won.

Anthony Haruna to je oga awon olopaa iyen DPO ni agbegbe naa lo saaju awon omoose loo mu awon asewo naa, ariwo ise esu ni, ise esu ni won pariwo titi ti won fi de tesan awon olopaa.

Komisanna awon olopaa nipinle Ogun, Illiyasu Ahmed ti pase pe ki won maa ko awon asewo naa bo ni Eleweran nibi ti iwadii yoo ti bere ni pereu. Bakan naa ni won ti gboku Adeyinka loo si mosuari.

No comments:

Post a Comment

Pages