Askari Onifuji |
Latigba ti Alaaji Wasiu Ayinde ti so
itan pe Oloogbe Alaaji Sikiru Ayinde Barrister ko lo da fuji sile, to si ti di
ariyanjiyan laarin egbe onifuji iyen FUMAN. Idi niyii lawon kan fi da igbimo
sile lati fidi okodoro mule lori nnkan to fa awuyewuye naa ati pe ta lo da orin
ti gbogbo won n ko doni in sile. Okan lara won ni Alaaji Adeyinnka Isola topo
awon ololufe e mo si Askari, to si tun je igbakeji gomina fegbe naa nipinle
Eko, ba oniroyin wa, BO SE RI soro lori idi ti wahala fi n sele ni
agboole orin fuji ati ibi tawon kan wa lori oro naa. E kaa bo se lo.
Oruko mi ni Alaaji Adeyinnka Isola topo mo si Askari to n ko fuji. Bi mo se n sise olopaa bee ni mo n korin fuji, nitori ebun ati ife ti mo ni si orin naa.
Oruko mi ni Alaaji Adeyinnka Isola topo mo si Askari to n ko fuji. Bi mo se n sise olopaa bee ni mo n korin fuji, nitori ebun ati ife ti mo ni si orin naa.
Idi ti kaseeti orin tuntun mi ko fi tii
jade.
Latodun to koja lo ye ki n ti gba
kaseeti tuntun jade gege bi mo se seleri fawon oloolufe mi sugbon awon idiwo
kan lo sele, sugbon mo dupe lowo Olorun pe titi osu keje odun yii, orin naa yoo
jade, nitori a ti base de ibi to lapeere.
Ipade irepo ti Wasiu Ayinde pe si Ijebu
Ode
Gege bi eyin naa se mo lodun to koja ni
Alaaji Wasiu Ayinde pe ipade irepo laarin awa onifuji si ile e ni Ijebu Ode,
ibeeere mi nip e se irepo naa ti wa wa bayii, nitori eni to pe ipade ti ko tii
pe osu mefa toun naa ti bona min in yo lati da nnkan ru. Irepo ko le wa laarin
wa,ayafi tab a maa tan ara wa je,awon la n wo gege bi asaaju to ye lati maa fi
se awokose sugbon peluu eyi ti won se, to si ti pin awon onifuji si wew, emi ko
ri abayori irepo kan ninu egbe FUMAN..
Mo kere lati so itan fuji.
Bo tile je pe awa kere lati so itan
fuji sugbon awon agba maa n soro kan pe bomode ko ba ba itan yoo ba aroba,
aroba sin ii baba itan.Bee ni won tun maa n so pe gbogbo omo to ba fee je ogun
kogun, itankitan ni yoo maa pa. Bi a ba ri enikeni to ba so pe Barrister
ko lo da fuji sile, e je ki onitohun fun wa aridaju ati eri gidi to fi le gbe
oro e leyin. Ninu itan ta gbo, ta de ba, ta si mo je ki a mo pe awon ti Wasiu
Ayinde menuba to daruko Sakara ni won n ko. Eni to ko Sakara ati Fuji iyato wa
nibe. Awa o gbo ninu itan pe Alaaji Ayinde Barrister ko Sakara, won ji were ni,
awa naa si ree, a ba won ji were ri. Sugbon nipa orin Fuji,Alaaji Ayinde
Barrister gan so ninu orin e kan pe tab a ri enikan,to so pe oun ko fuji saaju
oun, ki won ni ko mu eri wa,o salaye pe rekoodu to n se lodun bayii ree, to pe
ni Fuji Organisation. Lawa naa fi so pe bi enikan ba wa to pe ara e lonifuji
saaji Barrister k obo sita sugbon ti ko ba ti si ori eri taw a duro le lori nip
e Ayinde Barrister lo da fuji sile. Ninu itan gan an, ki Wasiu Ayinde funra e
to maa ko fuji, o niye rekoodu fuji ti Barrister ti gbe jade.Ni ero okan mi,
itan ti KWAM 1 pa ko fi gbogbo ara to si won lenu.
Awa kan si n gbe igbese lori itankitan
ti Wasiu pa
Loooto lawa kan wa to je pe latigba ti
Wasiu ta ka kun asaaju wa ti pa itankitan lati bere igbese lee lori lara e ni
eyi temi naa n so yii lati pariwo faraye.Nitori gbogbo nnkan ta ba se itan yoo
so lojo iwaju. Awa kan duro pe ko si elomin in to da fuji sile bi ko se Alaaji
Sikiru Ayinde Barrister.Awon bii Obesere, Fancy Aye Alamu, Iyanda Sawaba naa ti
so pe Olorun Fuji ni Oloogbe sikiru Ayinde Barrister.Opolopo awon eeyan naa lo
ti fehonu won han sii peluu. Sugbon kinni kan ti mo fee kawon eeyan mo nip e ti
ikunsinu ba tie wa laarin awon eeyan meji ti Olorun ba si tip e enikan sodo, se
o ye kka tun maa ba oku orun wijo.Boya won de fee da egbe ti won sile ki won pe
ni FUJA ni awa o le so, ni temi fuji lemi n ko, ko si selomin in to da sile ju
eni ti mo ti daruko loo.
Erongba Alaaji Kollignton lori oro yii.
Ni nnkan bi ose meloo kan seyin lawa
igbimo kan ti a yan pe ta ba ri enikeni to ni eri pe Barister ko lo da fuji
sile, ko bo sita, se eyin naa mo pe ore ni Alaaji Siriku Ayinde Barrister ati
Alaaji Kolligton Ayinla, bee ni won tun je orogun si ara won. Sugbon Kolligton
gan maa n so pe Barrister lo wa pe oun pe Kola,iwo naa maa bow a korin, eyi
fihan pe Barrister ti wa nidi orin ki Kolligton to bere. Funra kolligton naa lo
maa n so pe ki Olorun forunke Sikiru o, oore kan laye to se oun, toun ko le
gbagbe nip e o mu oun kuro lenu ise soja wa maa korin, toun fi deni Pataki loni
in. Bi a bat un wo, ko si ninu itan pe Kolligton Ayinla saaju Barrister gbe
rekoodu jade.oro ti so ara e tele.
Askari ati Olubadan |
Ariyanjiyan nise orin fuji laile
Bi emi se n wo, gbogbo nnkan to jo mo
ise fuji latile lo nii se peluu ariyanjiyan,bi yoo si se maa loo ni, nitori bi
agboole fuji ba yanju a je pe iku n de loo diedie niyen. Ariyanjiyan yii gan lo
n je kawon eeyan maa gbo wa, eyin naa e rii pe nigba ti Wasiu ju bonbu kale,
opo awon te gbo lagboole fuji ni won n jade soro sita.Kii se epe lo n jaw a bi
ko se ilana ati Isenbaye ta fid a fuji sile ni. Laipe yii ni Obesere gbe
kaseeti jade, awon to gbo ti mo pe o ti di awon oro kan sinu tele sugbon to je
pe akoko yii lo hu jade, bee lawon olorin min in naa tun ti wa ni studio bayii
lati so tenu won. Emi gan funra mi ninu rekoodu mi to maa jade yii, emi naa ko
sibe pe ki won maa fi itankitan ba agboole fuji je.
Awon asaaju nidi ise fuji lo mu
ifaseyin ba orin kolabo. .
Se e ri nnkan to sele nipa orin kolabo
nip e awon akuko gagara ni ko fee ki kekere ko, awon lo wa nidi orin kolabo
yii.Emi ti maa n so ninu egbe w ape ko rorun fun w ape ise ta ba ni lowo, ta o
fi han omode,ko dara to. Ka ni igba ti Barrister wa laye, ko gba awon to ku
laye lati maa korin fuji,fuji ko le debi to de loni in sugbon olorin kekere
tirawo e yo gbeyin lawon Shanko, bee ba pade e gan loni in, oun naa ti di Baba.
Ko si idi kan pato ta fi le fofin de kolabo sugbon awon eeyan kan lo wa nidi
e.Nitori ko le je pe awon nikan lawon eeyan yoo maa gbo.awon nikan ni won yoo
maa ri ode loo ti ko si ye ko ri bee. Awon ti gbagbe pe igba nile aye, aye yii
ko duro, to ba to akoko igba kan,won ni gburo won mo.Nitori e lo se ye ki won
maa sagbateru awon to n dide bo leyin.
Awon kan maa n lo agbara won lati maa
je ki kaseeti omo egbe e jade.
O maa n sele daadaa,orisi ona ni won n
gba se, won n ba iru ise eni bee yen je nipase maketa, bee ni won tun se nipase
awon ti yoo ba pin in rekoodu e, bakan naa, won tun maa n se lati maa je ko tie
rii se patapata. Sebi anfaani ki onifuji sise ni kawon eeyan gbo, ki won si
raa,nigba tawon egbe kan wa ti won mo pe o ye kawon ta oja,amo ti won ko ti won
ko ra oja naa.Awon eeyan ta n so naa ni, awon akuko gagara na ni. Odun meloo ni
won fee si se iyen, bawo ni egbe naa se fee ni ilosiwaju, oju orun teye fo lai
kanra, o ye ka gbara wa laye,igba kan ife yen wa ta jo n loo. Yato sigba kan to
je pe owo to ye ka maa fi bara wa se oogun la fi n se, amo bayii, tawon
onisegun gan ti n loo si ori redio, telifisan ati pepa loo polowo, ki la wa n
ba ka. Sugbon Osupa ti ko lorin o, pe eni to fee sinku egbon e to bo sihoho,
loju aburo apeere pe bi won yoo se se oun naa ni,Ohun tawon akuko gagara yen n
so nip e niwongba tawon naa ba ti yeye asiwaju, o daju awon omoleyin won naa
yoo se bee fun won.
Awon asaaju wa ko fun wa lanfaani lati
ba ijoba soro.
Awon anfaani to ye kawa omo egbe
onifuji ba ni lati so edun okan wa fun ijoba, awon akuko gagara yii naa ni ko
je ka loo,won ti se debi pe ti ko ba ti je awon, ijoba ko gbodo gboro tabi edun
okan wa. Nigba to si je pe awon lo mo eeyan nibe, ti won sise peluu won,to ye
ki won loo lati ran omo egbe lowo, se ni won duro niduro ibe lawon ti jeun,
awon ko le ja fomo egbe Kankan. Ka ni bi won se sunmo ijoba ni won so edun okan
wa fun won, ati nnkan ti won fee ki won se fun wa,o seese kawon isoro ta n koju
nipa pairesi dopin lagbo ariya. O da mi loju pe ka ni Barister si wa laye tawa
omo egbe wa ti loo ba nipa awon isoro ta ni, mo mo pe yoo ti lo agbara e lati
pe awon to mo nijoba, nitori awon naa mo pe ojo ti n dale fawon.Sugbon eni ta
pe lasaaju ja funra e ni.Asiko ipolongo lawon oloselu maa mo pe onifuji wa,
koda gan kii se gbogbo wa.
Idi ti mo fi pade
sileewe
Bi mo se n ba yin soro lowo yii,emi naa
ti pada sileewe giga yunifasiti ti Ago Iwoye nibi ti mo ti n kekoo nipa isakoso
okoowo iyen Business Admin, idi ni pe mo rii pe oju tawon eeyan maa fi n wo
awon onifuji kii dara to nipa iwe, eleekeji nip e won ki fi bee fipo gidi loo
wa laarin apapo egbe olorin. Mo fee mu da yin loju pe latigba ti egbe PMAN ti
wa, omo egbe wa Kankan ko se aare egbe naa ri. Pabanbari e nip e mo nii lokan
lati se oselu lojo iwaju.
No comments:
Post a Comment