Kaseeti orin mi to maa jade laipe yii yoo tun gbokiki mi ga - Wale Thompson - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 31 May 2017

Kaseeti orin mi to maa jade laipe yii yoo tun gbokiki mi ga - Wale Thompson

Bi won ba n so nipa osere fuji tokiki e kan, okan lara won ni Wale Thompson topo awon ololufe e mo si Lalale Fraide,sugbon fun bi odun meloo kan seyin lawon eeyan ko gburo okunrin naa mo, bawon kan se n so pe ko korin mo, bee lawon kan so pe omo bibi Ijebu Igbo naa ko gbe lorile ede yii mo. Sugbon lose to koja lohun ni oniroyin wa, salabapade okunrin yii niluu Abeokuta nibi to ti so idi e tawon ololufe e ko fi gburo e ati ise tuntun to sese fee gbe jade bayii. Eyi ni oro to ba wa so.

Wale Thompson
Bi mo se bere.
Oruko mi ni Wale Thompson tawon eeyan mo si Mista Lalale Fraide, Omo bibi ilu Ijebu Igbo ni mi.Mo loo sileewe alakobere St Lukes Anglican School ati ileewe girama Abusi Edumare Accademy niluu naa,leyin naa ni mo bere ise orin lodo Baba mi tawon n je Popular Jingo,nitori ilu mon on ka osere juju ni won nigba naa.

Bi mo se bere ise orin.
Nigba ti mo ti wa nileewe ni mo ti n ta gita leyin Baba mi, Gbolagade Amiwo tawon eeyan mo si Popula Jingo niluu Ijebu Igbo.Mo wa ninu egbe won titi ti mo fi pari iwe mewaa. Bi mo se setan ileewe ni mo loo kose awon to n tun jenereto se, mi o lo ju osu mefa loo ti mo fi kuro nibe. Asiko ti mo n kose naa, ni mo loo gbadura fun itoni lati odo Olorun, nibe ni won si ti so fun mi pe ko sise mi ti mo le se ju ise orin loo, idi niyii ti mo fi gba ruku tii, ti mo mu ise orin juju  ni okunkundun.

Awon olorin ti mo ti sise labe won.
Awon ti mo sise labe won, ti mo n ta gita leyin won, ko to dip e emi naa da temi sile tie po.Lara won ni Micho Ade,Oloogbe Handsome Wale Abiodun,Ahihinrere Dele Ojo, Mama wa, Ajihinrere Bola Are atawon min in ti mi o ranti.Lati odun 1983 ni mo ti n ta gita leyin Baba mi titi di 1985,leyin e naa ni mo wa peluu awon ti mo so yii, ko to dip e mo da temi sile lodun 1989,ti mo ti n da jade.

Kaseeti ti mo ti gbe jade
1994 ni mo gbe  kaseeti akoko jade ti mo pe akole e ni my Time,leyin naa mo tun ti se kaseeti marun un leyin e, sugbon elekefa e lo maa jade ninu osu keje odun yii lagbara Olorun.

Idi ti won fi n pe mi ni Mista Lalale Fraide.
Imisi yen wa nigba ti okan lara awon ololufe mi to saaba maa n wa sibi ti mo ti n sere ni alaale Fraide nibi kan ni Eko ti kii sunle gbogbo nnkan to n se yii maa n bi iyawo e ninu, to si n fa ede aiyede laarin won.Tiyawo pariwo sit ape oko oun maa foun sile ni alaale Fraide, kii wa sile wa sun. Okunrin yii wa je eni ti mo mo daadaa,to maa n wa sibi ti mo ti maa n sere.To ba si ti way ala ko da wa tabi ko wa pekuu awon ore e okunrin, kii se pe o gbobinrin wa.Orin mi lo maa n wa gbo, nitori o nifee mi. Ohun lo faa ti imisi orin yen fi wa lodun 1999 nigba to di 2000 lawon eeyan ba gba ti okiki mi tun fi kan.Latigba naa ni won ti n pe ni Mista Lalale Fraide.

Iriri mi nidi ise orin Juju.
Iriri mi po lorisiirisii,sugbon mo dupe lowo Olorun,nitori oro mi dabi ori to ti gun igi, ti ori naa ko fo, o ye ko maa fojoojumo dupe.Nigba ti mo bere ti ko tii si irinse,ti ko si moto, tawon eeyan ko sit ii da wa mo,ori la maa fi n ko irinse loo sibi tab a ti fee sere, igba min in wa to je pe a ko ni rowo mu bo. Igba min in wa ti mo maa n sere leemeta lojumo, aaro, osan ati ale,to je pe a ko ni rowo muu bo, gbese la tun maa n ko ara wa si.Mo tun ranti lopo igba tab a loo sere, ti moto ba je loju ona, tab a debi ibi tab a ti fee sere, se lawon to pe wa, a fee na wa pe a pe, won kii fee gbo pe nnkan bayii lo sele loju ona. Sugbon iriri ti mi o le gbagbe ni ijamba moto to sele si mi lodun 2002 nigba ta n bo nibi ta ti loo sere ni Ibadan nibi ti meji ninu awon omoose mi ti ku, emi gan funra mi, opelope Olorun lo ko mi yo lojo naa.

Mi o kabamo pe mo n koriin juju
Peluu gbogbo ipenija ti mo ti koju, ati tijanba moto to sele, ko sigba kan ti ko kabamo tabi pinnu lokan mi lati fi ise orin juju sile, nitori ko sise teeyan ba se nile aye yii,ko maa nidojuko ati pe tita riro ni a n kola.

Idi tawon eeyan ko fi gburo mi mo.
Nigba tijamba moto naa sele,a ko le se ipolowo rekoodu tuntun ta sese se nigba naa,ijanba naa lagbara debi pee mi naa loo siluu oyinbo ti mo loo toju ara mi,leyin ti mo gbadun, mo duro sibe fosu mefa nibi ti mo tun ti sere peluu awon omoose mi ta jo lo. Eyin naa mo oro awon eeyan wa,ti olorin kan ba wa ti won gbo nipa e daadaa tele, ti won ba wa gbo pe o loo siluu oyinbo fosu kan si meji, ero okan won nip e boya onitohun ko wale mo. Nigba ti mo pada de lati iluu Oyinbo,opolopo ipolowo la ti se lati je kawon eeyan mo pe Nigeria la n gbe sugbon opo to ti gbo alo, ni won ko gbo abo.Ati pe opo orin kaseeti ta gbe jade leyin naa ni ipolowo ko to fun won gege ba se maa n se tele, awon idi abajo tawon eeyan fir o pe boya mi o sere mo, tabi pe won ko gburo mo.Sugbon ni bayii,peluu atileyin Olorun atawon oniroyin mo nigbagbo pe okiki rekoodu to sese fee jade laipe yii ta pe akole e ni Destiny maa ju ti lalale Fraide loo.

Nibi torin Juju de.
Ibi tawon Baba wa King Sunny Ade,Ebenezer Obey,Shina Peters ba orin Juju de ko kere, o si lapere,ti won ko si duro.Bee naa ni emi atawon elegbe mi naa sise takuntakun lati le je ki ojo iwaju orin juju da ju bo se wa bayii loo.

Orin Juju ko nii se pelu esin
Iro to jinna sooto ni pe elesin kristeni ni Juju wa fun, ko si nnkan to jo, opo awon agba onijuju bii Ahuja Bello,YK Ajao atawon min in musulumi ni won ti won si se daadaa nidi ise naa.Idije kan ta n se lowo ti awon Goldberg se onigbowo e,obintin to jawe olubori nibe, Alaaja Buki, musulumi  ni oun naa.Orin teeyan ba nifee si, to sise le lori lati ko, lo le ko, Juju ko nii se peluu elesin.

Oju tawon obi mi fi wo ise orin ti mo ko.
Obi to ba nife omo e gbogbo nnkan to ba dara ni won yoo maa wa fun un,awon obi mi paapaa Baba mi won ni lokan pe ti mo tie korin,mo gbodo nise min in peluu e.Mo si fi ye won pe, mo maa sise nigba ti mo ba ti n korin daadaa, mo maa wa ise ti mo maa se pelu e. Sugbon ohun tawon n fee nip e boya ki n ko ise owo tabi ki n loo sileewe, lati ko nipa dokita, loya tabi osise banki, nitori mo ti fona mi le OLorun lowo nibere aye mi, ko je ki n fakoko sofo Kankan.

Ko sigba tinu mi kii dun
Gbogbo igba ni inu mi maa n dun,ti mo ba ti ji ni owuro, mo maa n dupe lowo Olorun pe o se o ka mi kun alaye.

Ojo tinu mi baje ju
Ojo tinu mi baje ju lojo tijamba moto sele,okan mi baje ju,ki Olorun maa je ki n ri iru e mo.Ijamna to mu emi eeyan meji loo,ti won sun mo mi,to je pe gbogbo igba a jo maa n wa ni,bi mo se n soro yii, o si n ba mi lokan je.

Ibi tise orin ti gbe mi de
Mo dupe lowo Olorun pe ise orin Juju ti mo n ko ti gbemi de ibi re, to sit un gbe mi de awon orile ede bii America, Canada, Dublin atawon min in ti mi o ranti.

No comments:

Post a Comment

Pages