Awon omoleyin Yayi ti eka Abeokuta sepade nla nile Osoba - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 5 July 2017

Awon omoleyin Yayi ti eka Abeokuta sepade nla nile Osoba

Lojo Isegun Tusde tii se ojo kerin osu keje ni awon omoleyin oludije fun ipo gomina fodun 2019 labe egbe oselu APC, Seneto Solomon Olamilekan Adeola tawon eeyan mo si Yayi sepade nla kan nile Agba oselu nni, Oloye Segun Osoba to wa niluu Abeokuta.

Pataki ipade won ni bi won se n mura sile fun ibo to n bo naa ati bi oludije won yii yoo se se itewogba nipinle Ogun. Bo tile je pe ohun ti BO SE RI gbo nip e awomn eeyan naa ti sise jinna debi to lapeere.

Bakan naa ni iwadii tun fi ye w ape opo awon oloselu ti won leyin Amosun tele ni Abeokuta ni won ti darapo mo Yayi lati ba sise po, bee naa lo si je awon  ti won tun ti figba dipo mu ninu egbe oselu PDP ni won ti tori okunrin oloselu omo Yewa naa darapo mo APC bayii ti won jo se ipade po lojo naa.

Ninu oro ti okan lara awon oloselu naa ba BO SE RI so ni pe igba die naa lo ku ti ipolongo yoo fib ere ati pe awon agba bo won ni ati okeere ni oloju jinjin ti n mu ekun sun, idi niyii tawon fi tete bere ise abele naa tawon ko si fee ko bawon lojiji.

Won ni inu awon dun pe Amosun naa ti so pe Yewa ni ipo gomina naa kan, awon si ti mo pe ko si Yewa min in naa bi ko se Yayi, won ni asiko oro si n bo, takoko ba to awon eeyan yoo ri imole.

Bee ni won tun seleri pe awon yoo rip e awon gba gbogbo awon Abeokuta ati agbegbe e fun Yayi ki akoko ibo to pe.

Capt; Lara awon omo eyin Yayi ti won wa nibi ipade lojo naa.

No comments:

Post a Comment

Pages