PDP lawọn ara ipinlẹ Ọyọ yoo dibo fun ni 2027, ojoojumọ lawọn eeyan n dara pọ mọ ẹgbẹ wa- Olunlọyọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 18 October 2026

PDP lawọn ara ipinlẹ Ọyọ yoo dibo fun ni 2027, ojoojumọ lawọn eeyan n dara pọ mọ ẹgbẹ wa- Olunlọyọ


Ọlawale Ajao, Ibadan

"Bi Gomina Ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinia Ṣeyi Makinde, ṣe  lọọ dara pọ mọ ẹgbẹ oṣelu tuntun ko le ṣakoba kankan fun ẹgbẹ PDP ipinlẹ naa lasiko idibo ọdun 2027."

Oludije fun ipo sẹnetọ Ẹkun Aarin Gbungbun Ipinlẹ Ọyọ (Oyo Central Senatorial Constituency) lorukọ ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party (PDP), Ẹnjinia Ayọbami Akinyọde Olunlọyọ, lo sọrọ yii ninu ipade oniroyin to ṣe n'Ibadan lọjọ Sannde, Ọjọ Kejidinlogun, Oṣu Kẹwaa, Ọdun 2026 yii.

Ẹnjinia Olunlọyọ jẹ ọmọ ọkan ninu awọn ọmọ bibi inu Ọmọwe Victor Ọmọlolu Olunlọyọ, ẹni to ṣe gomina ipinlẹ Ọyọ lọdun 1983.

Nigba to n sọrọ lori ipo ti ẹgbẹ oṣelu PDP wa ni  Ipinlẹ Ọyọ lọwọlọwọ bayii, ọmọ baba to ti figba kan ri ṣe gomina ipinlẹ Ọyọ yii ṣalaye pe bi Gomina Makinde ṣe kuro ninu ẹgbẹ naa lati lọọ dara pọ mọ ẹgbẹ tuntun ko yi ẹgbẹ PDP lorukọ pada, bẹẹ ni ko ni ki ẹgbẹ ọhun ma ṣaṣeyọri.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, "Bi Gomina Makinde ṣe kuro
ninu ẹgbẹ yii ko le ṣakoba fun wa, orukọ ẹgbẹ PDP ko yi pada. Awọn eeyan o gbagbe ẹgbẹ PDP nitori ẹgbẹ ju ẹnikẹni lọ.

Awọn kan ko le kuro ninu ẹgbẹ ki wọn ro pe ẹgbẹ ti parẹ, PDP wa sibẹ, o duro digbí.

"Awọn araalu la gboju le. Awa yii kii ṣe opurọ. Ọpọ eeyan ni ko mọ pe lojoojumọ lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu mi-in n waa darapọ mọ ẹgbẹ PDP, o di ọjọ ibo ko too pada waa ye wọn pe tiwa lawọn ara ipinlẹ Ọyọ n ṣe.

Nigba to n sọrọ lori idi to ṣe jade lati du ipo sẹnetọ, Olunlọyọ sọ pe "Emi kii ṣe oloṣelu, oniṣẹ ilu ni mi.

"Awọn oloṣelu ni wọn maa n wa ọna lati jokoo ohun to tọ si awọn araalu, ṣugbọn nṣe lẹni to ba jẹ oniṣẹ ilu maa n ṣiṣẹ sin awọn araalu.Idi niyẹn to fi jẹ pe taa ba fẹẹ wo igba ti Naijiria daa, ẹyin la maa wo, kii ṣe iwaju.

"Mo maa mu ọrọ awọn ọ̀dọ́ ni pataki nitori awọn ọdọ ni wọn ko ida aadọrin (70%) ninu awọn ọmọ Naijiria. Bakan naa la o nii fi ọrọ awọn obinrin ṣere rara.

Ni pataki julọ, idi ti mo ṣe n dupo lati lọọ ṣoju ẹkun idibo Aarin Gbungbun Ipinlẹ Ọyọ nIleegbimọ aṣofin Apapọ niluu Abuja ni lati ṣofin to maa mu ki awọn ara ẹkun idibo mi janfaani eto ilera, eto ẹkọ, eto aabo, igbelarugẹ eto ọgbin, eto ọrọ aje, ati idagbasoke imọ ẹrọ."

O ṣalaye siwaju pe "Ipo sẹnetọ ti mo n du yii, lati mu ayipada rere ba agbegbe mi, ati Naijiria lapapọ ni.

"Bii apẹẹrẹ, owo ti wọn ba n fun aṣofin kọọkan gẹgẹ bii owo idagbasoke agbegbe wọn, nṣe lo yẹ ki wọn maa kede rẹ fun gbogbo aye gbọ. Eyi yoo jẹ ki awọn aṣofin le mura lati maa na owo naa bo ṣe yẹ, awọn araalu paapaa yoo le maa ṣe igbelewọn boya iṣẹ ti awọn aṣofin wọn n ṣe ba to iye owo ti wọn n gba.

"Emi kii ṣe ẹni ti yoo maa jokoo si Abuja lojuloojumọ, ọfiisi lasan ni Abuja jẹ, aarin awọn araalu ti wọn dibo yan wa gan-an ni iṣẹ wa.

"Nitori idi eyi, awọn ọjọ ti ijokoo tabi nnkan pataki ba wa nIleegbimọ aṣofin nikan ni maa fi maa wa niluu Abuja, gbogbo ọjọ yooku, ẹkun idibo mi tii ṣe Aarin Gbungbun Ipinlẹ Ọyọ (Oyo Central Senatorial Constituency) ni maa maa wa, ti awọn to dibo yan mi yoo le maa ri mi lati ba mi sọrọ nipa ohun ti wọn ba fẹ."

No comments:

Post a Comment

Pages