O sọrọ yii nibi ayẹyẹ ifilọlẹ ibẹrẹ ipolongo fun ipo aṣofin ọhun eyi to waye niluu Eko, O sọ pe ni idile kọọkan to jẹ ọmọ bibi Eko, ki wọn lọọ ṣe ipade.
O ni ' Gbogbo ẹyin oloye ni Eko, ẹ jẹ ki oju ti yin, ẹ ko wa lẹru, ati jade nibẹ, ẹ ko le lọ mọ. Wọn a wa lọ maa dọbalẹ gba dọla lagbegbe kan ti wọn pe ni Ikoyi"
Salvador tun sọ pe, "Awọn ẹbi gidi ni Eko yii, bi wọn ko ba ro tawọn ọmọ wọn, awọn baba wọn ti jẹ tawọn ọmọ wọn mọ aye, ki ẹ ma jẹ tawọn ọmọ ọmọ yin mọ o'
O waa bẹrẹ si nii pe ẹbi kọọkan ti wọn jẹ ọmọ bibi niluu Eko, lati tete ṣatunṣe ki wọn bọ lọwọ awọn oloṣelu to ti sọ wọn di ẹru.
Oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu NDC tun fikun ninu ọrọ ẹ pe lara ohun akọkọ to wa lọkan oun bi wọn ba le dibo foun wọle ni fi ẹhọnu han nile igbimọ aṣofin lori bi wọn ṣe n ṣe awọn ọmọ orileede yii ti wọn wa loke okun niṣekuṣe, eyi to nijpba APC to wa lode kuna lati ṣe.
O sọ pe a gbọdọ fopin si bawọn araalu ki i ṣe mọ aṣoju wọn, to jẹ pe bi wọn ba debẹ tan oorun ni wọn lọ maa n sun ti wọn ko mọ ju ki wọn kan pin owo lọ.
Salvador tun ṣalaye siwaju pe nnkan to ṣe pataki fẹni to ba jẹ aṣoju ni lati jẹ kawọn eeyan ẹ mọ mudunmudun to wa ninu ijọba tiwa-n-tiwa, nipa wiwa ọna abayọ si isoro to n koju awọn eeyan ẹ.
O wa gba awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu NDC lamọran lati ma ṣe jẹ ki wọn tun jẹ wọn mọ aye ninu ibo to n bọ naa.
No comments:
Post a Comment