Fun imurasilẹ ipolongo ibo: Paṣeda ṣepade pọ pẹlu awọn oloye ẹgbẹ oṣelu NDC nipinlẹ Ogun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 17 October 2026

Fun imurasilẹ ipolongo ibo: Paṣeda ṣepade pọ pẹlu awọn oloye ẹgbẹ oṣelu NDC nipinlẹ Ogun.

Lati le gbaradi fun idibo ọdun to n bọ ninu ẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress, NDC, nipinlẹ Ogun, agba oṣelu nni, Ọtunba Olurotimi Paṣeda ti ṣe ipade pọ pẹlu awọn oloye ẹgbẹ naa.

Ipade ọhun to waye nile ẹ to wa ni Omu Ijẹbu, nibẹ ni gbogbo awọn oludije ti wọn fẹẹ kopa labẹ ẹgbẹ oṣelu ọhun ti peju pesẹ.

Ninu ọrọ ẹ lọjọ naa Ọtunba Paṣeda ti rọ gbogbo wọn pe akoko ti to bayii ki wọn wa ni iṣọkan  ki wọn si jọ forikori pẹlu ifẹ lati fi jọ ṣiṣẹ pọ lakooko ipolongo yii.

O sọ pe, "Idi pataki ti ipade yii fi waye ni lati gbimọ pọ, ka forikori bi a ṣe le tẹsiwaju, ki a si rii pe a ṣatilẹyin nla fun oludije wa fun ipo aarẹ".

Lori ipo oludije gomnina nipinlẹ Ogun  Paṣẹda sọ pe ko sibi ti oṣelu abẹle ko si, o ni bo tilẹ jẹ pe awọn niṣoro lori oludije ṣugbọn awọn ṣi ọna abayọ fun ipo ọhun.

Nibi ipade ọhun lo ti faye gbogbo ọmọ ẹgbẹ naa lati sọ asọye lori bi wọn ti ṣe wa ni imurasilẹ, pẹlu ileri pe ẹgbẹ naa rọwọ mu nibi ibo gbogboogbo ti yoo waye lọdun 2027.


No comments:

Post a Comment

Pages