Alakoso ẹgbẹ ọhun nipinlẹ Ogun, Oloye Wuraọla Adeṣina lo ṣagbekalẹ awọn oloye ọhun nibi ipade kan to waye ni Ogun East.
Ninu ọrọ obinrin naa lo ti sọ pe gbogbo awọn oloye ẹgbẹ Nigeria Democratic Congress NDC, nipinlẹ ni wọn wa nipo wọn ninu Obidient Movement.
O ṣalaye siwaju pe eyi yoo jẹ ki ajọṣepọ itankalẹ ẹgbẹ ọhun tubọ tan kalẹ sawọn wọọdu atawọn ẹka gbogbo to wa nipinlẹ Ogun.
Adeṣina tun sọ pe apa keji ipade ọhun ni yiyan awọn oloye ẹgbẹ sawọn ijọba ibilẹ, eyi to tun ni awọn oloye ẹgbẹ NDC lawọn ijọba ibilẹ ọhun tun ni yoo maa dari Obidient.
A o ranti pe lọjọ kẹtala, oṣu yii ni Dokita Mosses Paul yan Oloye Wuraọla Adeṣina gẹgẹ bi alakoso ẹgbẹ naa nipinlẹ fun imurasilẹ ibo gbogboogbo ọdun to n bọ.
Gbogbo awọn oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu NDC ni wọn wa nibẹ lọjọ naa,erongba wọn lọjọ naa ni lati forikori papọ fun ibo 2027.
Nipa idasilẹ Movement Obidient, wọn lo jẹ ẹgbẹ to ṣiṣẹ fun iṣejọba rere fawọn araalu, eyi to ni awọn olori rere ti wọn le mu ifọkanbalẹ fawọn araalu, lati ṣatilẹyin fun Peter Obi gẹgẹ bi aarẹ ati Sẹnetọ Rabiu Musa Kwakwanso, igbakeji aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu NDC.
No comments:
Post a Comment