Mo ṣetan lati mu idagbasoke ba agbegbe Ewekoro/Ifọ -Ọnarebu Ademọla Ọlatunbọsun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 23 October 2026

Mo ṣetan lati mu idagbasoke ba agbegbe Ewekoro/Ifọ -Ọnarebu Ademọla Ọlatunbọsun

Ọnarebu Ademọla Ọlatunbọsun, oludije fun ipo aṣoju-ṣofin fun ẹkun Ewekoro/Ifọ, labẹ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC, ti ṣeleri lati tubọ mu idagbasoke ba agbegbe naa, ti wọn ba le dibo foun ninu ibo ti yoo waye lọdun 2027.

Ọlatunbọsun ṣalaye ọrọ yii lakooko to ba oniroyin wa sọrọ lori idi to fi jade dupo, o sọ pe ọpọ iṣẹ lo wa lọkan oun fawọn araalu to n fẹẹ lọ ṣoju fun ni eyi ti yoo mu irọrun ba wọn.

O sọ pe agbegbe Ewekoro/Ifọ wa lara ibi tawọn eeyan pọ si nipinlẹ Ogun tawọn ileeṣẹ nla pọ si, idi niyii toun yoo fi ri pe awọn ohun imayedẹrun ko nii jẹ wọn niya.

Ati pe ohun akọkọ to wa lọkan oun bi oun ba wọle ni lati ṣepade pọ pẹlu awọn agbegbe kọọkan to wa labẹ Ewekoro/Ifọ lati mọ awọn nnkan akọkọ to jẹ wọn niya, toun yoo gbe lọ sile aṣoju ṣofin, ki wọn si bawọn gbe igbesẹ lee lori.

Ọlatunbọsun tun sọ pe," Mo mọ iyi araalu pupọ nitori aarin wọn ni mo n gbe nitori ẹ ni yoo ṣe ṣe pataki fun mi lati maa fikunlukun pẹlu wọn ni gbogbo igba, emi o lọ si Abuja lati lọọ ma sun lakooko tawọn akẹgbẹ ba n jiroro lori nnkan to jẹ awọn eeyan wọn lọkan."

O tun sọ pe o wu oun lọkan lati sin awọn eeyan oun bi wọn ba foun ni oore ọfẹ lati dibo yan oun wọle labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC.

Nitori oun mọ pe iṣẹ oun gẹgẹ bi aṣoju ṣofin ni lati sin awọn araalu, oun ko si nii ṣe nnkan ti ko ni jẹ koun lọ ba wọn lọjọ iwaju.

Ọnarebu wa fi idunnu ẹ han lori bawọn eeyan ṣe n tu yaya ti wọn si n fi atilẹyin wọn han si pẹlu.

O wa lo akoko naa lati gboṣuba fun Ọtunba Fẹmi Ṣoluade, to jẹ alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ fun ọpọlọ ti Ọlọrun fun un lati dari ẹgbẹ ADC nipinlẹ Ogun

Bakan naa lo rọ araalu lati dibo wọn fun ẹgbẹ ADC ninu ibo gbogboogbo ti yoo waye lọdun to n bọ.


No comments:

Post a Comment

Pages