Iru eeyan bẹẹ ni Ọnarebu Ọla Motunrayọ Oluṣọla, tọpọ mọ si Arikẹ Ayekootọ, oludije fun ipo aṣoju-ṣofin fun agbegbe Alimọṣọ, nipinlẹ Eko, labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC.
Akọni obinrin ni laarin awọn ẹgbẹ, oloṣelu to nimọ ati oye ni pẹlu, o si jẹ ẹni ti ọrọ ọmọnikeji ẹ maa n ka lara. Bẹẹ ẹlẹyinju aanu ni pẹlu.
Awọn to mọ Ọnarebu Oluṣọla lo mọ pe ẹni to ni itẹriba to si maa n bọwọ fawọn aṣaaju nibi gbogbo ibi to wa.
Gbogbo eyii lawọn ara agbegbe Alimọṣọ ṣe ṣatilẹyin nla fun un lati jade gẹgẹ bi oludije fun ipo aṣoju ṣofin niluu Abuja, wọn ni ko wa lọọ ṣoju awọn nibẹ, tawọn si nigbagbọ pe awọn ko nii kabamọ to ba debẹ.
Bẹẹ gẹlẹ naa ni Oluṣọla naa ti ni lọkan lati lọọ sin awọn eeyan ẹ, ko si mu awọn ohun idagbasoke wa fun wọn.
Obinrin bii ọkunrin naa sọ pe kin ni ọkunrin ṣe nile igbimọ aṣoju ṣofin tawọn obinrin naa ko le ṣe ju bẹẹ lọ.
Ati pe agbegbe Alimọṣọ ko kere nipinlẹ Eko, ilu to gbooro tawọn eeyan nla ti jade, tawọn ileeṣẹ nlanla wa nibẹ, idi niyii toun naa fi ṣeleri pe iṣẹ ati sin awọn eeyan ohun loun ba lọ ki i ṣe fun afẹfẹ yẹyẹ tabi koun kan lọọ maa jokoo tabi sun nibẹ.
Bo ṣe n ṣeleri pe gbogbo bi nnkan ba ṣe n lọ loun yoo ma jẹ kawọn toun yoo lọ maa ṣoju maa gbọ, ati pe akoko yoo maa wa lati jọ maa fikunlukun lori idagbasoke Alimọṣọ.
O ni bo ṣe jẹ pe oriṣii ẹya lo n gbe ni Alimọṣọ nitori idi eyi ko ni si nnkan to n jẹ ẹlẹyamẹya, oun yoo si rii pe ajọṣepọ ati ifẹ to danmọran wa laarin gbogbo wọn.
Akoko ti wa to bayii fun gbogbo ẹyin ara agbegbe Alimọṣọ lati ṣatilẹyin fun Ọnarebu Ọla Motunrayọ Oluṣọla, ti ẹgbẹ ADC, lati fi ibo yin gbe e wọle gẹgẹ bi aṣoju ṣofin niluu Abuja.
No comments:
Post a Comment