Ninu atẹjade kan t to fi sita lo ti beeere fun iwe toun kọ pe oun ko ṣẹjọ mọ pẹlu awọn ẹri ti wọn ba ni.
O ṣalaye pe iyalẹnu lo jẹ foun lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan-an,ọdun yii nigba ti agbẹjọro oun, Ọgbẹni Anderson Asemota, to parọ fun ile ẹjọ pe mo ni mi o ṣẹjọ mọ.
O sọ pe ko sigba tabi akoko toun pe lọya oun jokoo pe oun ko ṣẹjọ tsbi ko tẹsiwaju ẹjọ naa.
Ṣoluade sọ pe lati nnkan bii oṣu meji ni ara oun ko ya toun ko fi bẹẹ gbọ nipa ẹjọ naa ati pe oun ko baa sọ iye owo kankan pe oun ko ṣẹjọ mọ..
O wa pe agbẹjọro ẹ lati bọ sita ko wa nnkan to mọ ati idi to fi gbe igbesẹ ọhun laijẹ koun mọ si.
O ni ko wa mu awọn ẹri yala iwe, tabi igbohunsilẹ to tọka sii pe oun mọ lori bo ṣe gbe ẹjọ kuro nile ẹjọ.
O wa fun adajọ ẹ ni wakati mejilelaadọrin lati gbe awọn nnkan toun beere lọwọ ẹ silẹ nitori oun ko le gba ki ẹnikan ba oun lorukọ jẹ.
No comments:
Post a Comment