Awọn ọlọdẹ atawọn ẹya ti ki iṣe Yoruba fọkan Ṣẹgun Ṣowunmi balẹ lori ibo aarẹ Tinubu lọdun 2027. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 3 October 2026

Awọn ọlọdẹ atawọn ẹya ti ki iṣe Yoruba fọkan Ṣẹgun Ṣowunmi balẹ lori ibo aarẹ Tinubu lọdun 2027.

Ẹgbẹ awọn ọlọdẹ atawọn ẹya ti ki i ṣe Yoruba ti wọn gbe nipinlẹ Ogun, ti muu da Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, oludasilẹ 'The Alternative' loju pe gbogbo wọn ṣetan lati dibo wọn fun Aarẹ Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu fun ibo ọdun 2027.

Wọn sọrọ idaniloju yii nibi ipade ọtọọtọ to ṣe pẹlu wọn lonii niluu Abẹokuta, fun ti ipolongo lati ko awọn eeyan jọ, eyi ti Ṣowunmi ṣe kaakiri ipinlẹ Ogun.

Ẹgbẹ awọn ọlọdẹ lo kọkọ ṣe ipade pẹlu wọn ni gbọngan wọn to wa ni Itoko, nibi tawọn ọlọdẹ kaakiri ipinlẹ naa ti peju pesẹ.

Oludasilẹ ẹgbẹ ọna abayọ iyẹn The Alternative ti kọkọ fi ẹmi imoore ẹ han lori  bawọn ọlọdẹ ọhun ṣe tu jade fun ipade ọhun.

O sọ fun wọn pe idi pataki toun fi wa bawọn ni lati rọ wọn ki jade lọpọ lati dibo fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu fun saa ẹlẹẹkeji.

Ṣowumi fikun ọrọ ẹ pe oun fẹẹ ki ibo ọdun to n bọ yatọ gedengbe si ti tẹlẹ, nitori bawọn araalu ki i ṣe jade bi wọn ṣe ro lati dibo.

O mẹnuba awọn aṣeyọri nla tijọba Tinubu ti ṣe ni saa akọkọ to fi wa nibẹ, toun si nigbagbọ pe yoo tubọ ṣe ju bẹẹ lọ.

Nigba to n ba awọn ẹya ti wọn ki i ṣe Yoruba, ti wọn gbe ni ipinlẹ Ogun, o sọ fun wọn ki wọn ma ṣe ri ipadabọ Tinubu ẹlẹẹkeji gẹgẹ bi idena fawọn ẹya Igbo lọjọ iwaju.

Ṣowunmi sọ pe ki wọn jade lakooko ti ibo naa yoo waye, ki wọn si fi kaadi idibo wọn gbe Tinubu wọle.

O jẹ ki wọn mọ pe bi wọn ṣe n ṣatilẹyin fun Tinubu nibi ibo to n bọ naa iyẹn ko nii kawọn ẹya yooku ti wọn ba nii lọkan fawọn ipo ma fi erongba wọn han.

O wa rọ awọn eeyan ọhun paapaa awọn ẹya Igbo ki wọn ṣatilẹyin to gboogi fun Aarẹ Tinubu.

Ṣowunmi ṣọ pe oun mọ pe awọn eeyan naa ko doju ti oun ri nitori ẹ loun ṣe tun sa wa ba wọn lati jẹ ki ibo ọtẹ yii to ma gbe Tinubu wọle pọ ju ti tẹlẹ lọ.

Ninu ọrọ olori awọn ọlọdẹ atawọn ti wọn ki ṣe ẹya Yoruba, wọn ni ki Ṣẹgun Ṣowunmi fọkan balẹ, nitori awọn ti ṣetan lati dibo  wọn fun Tinubu ju bi wọn ṣe roo tẹlẹ lọ.

No comments:

Post a Comment

Pages