Ninu atẹjade kan ti wọn tun gbe jade laarọ yii ni wọn ti ṣalaye ẹ pe bawọn ko ba ni ẹri, awọn ko le sọ nnkan ti wọn sọ jade ọhun ati pe ko si nnkan ti wọn fọwọ bo nibẹ.
Wọn ni ṣe bi INEC ko ṣe gbe orukọ oludije wọn, Ladi Adebutu ati igbakeji ẹ jade laarin awọn oludije Gomina yooku ti wpn gbe jade, eyi tawọn iwe iroyin paapaa gbe jade, eyi ti wọn ẹka kejilelọgbọn, abala kin in ni ninu iwe ofin feto idibo gbe e lẹsẹ, ni wọn fẹẹ sọ pe ko ri bẹẹ.
Abi ile ẹjọ ijọba apapọ ti PDP gba lọ lati fi tako igbesẹ ajọ INEC lori bi wọn ṣe yọ Adebutu.Wọn ni ṣe lẹta ti ẹnikan torukọ ẹ n jẹ Tọpẹ Oluṣẹgun Peters kọ si ajọ eleto idibo nibi to ti fun wọn ni wakati mejidinlaadọta lati da orukọ oun pada gẹgẹ bi oludije gomina, lẹyinọrẹyin lo jẹwọ ni Abẹokuta pe oun ko gba fọọmu gomina rara.
Awọn ọọdunrun ọmọ ẹgbẹ PDP, LP, ADC, ti wọn darapọ mọ APC ni Ọdẹda.Nipa aarin gbungbun Ogun iyẹn Ogun Central, a gbọ pe igbẹjọ kan ti n lọ lọwọ, eyi ti yoo tẹsiwaju lọjọ kẹta, oṣu kọkanla, ọdun yii nile ẹjọ ijọba apapọ, laarin Iyabọ Ọbasanjọ ati Sogbẹsan Amọo ati ajọ INEC, eyi ti nọmba ẹ jẹ FHC/AB/CS/117/2026. Ohun ti wọn si jọ n fa ni pe boya orukọ oludije PDP naa jẹ orukọ ọmọ ẹgbẹ ti wọn fa kalẹ fun ajọ eleto idibo gẹgẹ bi ilana ofin ẹka kẹtadinlọgọrin.
No comments:
Post a Comment