Pẹlu bijọba ṣe fọwọ sii Ọtunba John Olumide Atanda Ọṣunṣina ti di ọba alaye tilu Ifọ Oṣomẹkun keji.
Bijọba Ogun ṣe buwọ lu ọba alaye tuntun ọhun da lori bawọn afọbajẹ ilu naa ṣe foun ṣọkan lati yan Ọṣunṣina gẹgẹ bi ori ade tuntun fun ilu Ifọ.
Eyi tijọba naa si fọwọ si gẹgẹ bi ilana ofin to nii ṣe pẹlu yiyan ọba alaye nipinlẹ Ogun.
Pẹlu ayọ ati inu dundun lawọn eeyan agbegbe marun un ti wọn wa labẹ Ifọ fi ki ọba tuntun naa ti wọn nigbagbọ pe yoo tubọ mu ilọsiwaju ati idagbasoke ba ilu naa lakooko to gori oye.
No comments:
Post a Comment